Ti wọn ba fi Sunday Igboho silẹ pe ko maa lọ bayii, ohun to maa ṣẹlẹ le ju eyi ti wọn ṣe nile ẹ n’Ibadan lọ-Falọla

Adefunkẹ Adebiyi

Agbẹjọro Oloye Sunday Adeyẹmọ, Dokita Malik Falọla ti ṣalaye fun ALAROYE pe bi awọn ba ni ki wọn fi Sunday Igboho silẹ ko maa lọ lọjọ ti awọn lọ sile-ẹjọ, afaimọ ki ohun ti yoo ṣẹlẹ si i ma buru ju eyi to ṣẹlẹ nile rẹ niluu Ibadan lọ.

Agbẹjọro naa to ba akọroyin wa sọrọ ni orileede Benin sọ pe ‘‘Bi ọmọde ba n gegi nigbo, agba lo maa n mọ ibi to maa wo si. Awọn adajọ kọṣẹ, wọn mọṣẹ, bi wọn ba le fi Sunday Igboho silẹ lawọn ọjọ ta a fi lọọ ṣẹjọ yẹn, nnkan to maa ṣẹlẹ nibẹ ko ni i daa.

”Eeyan bii ẹgbẹrun kan lo n wa si kootu nitori ẹ, awọn ẹlomi-in n lepa ẹmi ẹ. Ta a ba le tu u silẹ lọjọ naa pe ko rin laarin wọn, wọn aa yinbọn fun un,  a o si fẹ awọn iṣẹlẹ ti yoo ṣẹlẹ ti apa wa o ni i ka. Ta a ba ni ka fi Sunday Igboho silẹ pe ko maa lọ ni kiakia, ohun ti yoo ṣẹlẹ yoo ju ohun ti wọn ṣe nile ẹ n’Ibadan lọ.

”O le ṣeku pa a, o le ṣeku pa awọn mi-in laarin ilu, o le di ohun ti wọn n ba dukia jẹ, nitori ẹ ni a ṣe gbe Sunday lọ sibi ti aabo wa fun un, nitori bawọn ololufẹ ṣe wa fun un lawọn ọta ẹ naa wa.

”Ṣugbọn ki gbogbo wọn lọọ fọwọ wọnu, wọn ko ti i le ri Sunday lasiko yii.”

Leave a Reply