Gomina ipinlẹ Ogun nigba kan ri, Arẹmọ Oluṣẹgun Ọṣọba, ti sọ pe gbogbo ẹtọ pata ni Aṣiwaju Bọla Hamed Tinubu ni lati dupo aarẹ orilẹ-ede Naijiria lọdun 2023.
Ọkan pataki ninu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni Ọsọba, lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ laipẹ yii lo fidi ẹ mulẹ pe gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ naa ni ẹtọ daadaa lati dije, ṣugbọn Yoruba gbọdọ wa ni iṣọkan.
O ni “Titi di asiko yii, a ko ti i sọ pe ẹni kan bayii la fẹẹ lo nitori iru igbesẹ bẹẹ lasiko yii le da awọn eto kan ru. Ti a ba waa n sọ nipa ẹtọ ati kikun oju oṣunwọn, ojulowo ni Tinubu ninu ẹni to le bọ sigbangba dupo Aarẹ Naijiria.”
Ọṣọba ti waa ke si awọn Yoruba lati wa ni iṣọkan, ki ohun rere le to wọn lọwọ ninu ibo aarẹ to maa waye lọdun 2023. Bakan naa lo sọ pe asọyepọ yoo waye lati fa eeyan kalẹ ti asiko ba to.
Siwaju si i, o ni gẹgẹ bii ọkan pataki ninu ọmọ ẹgbẹ, ko ti i ṣeni kan bayii to ba oun sọ ọ pe oun fẹẹ dije dupo aarẹ lapa ọdọ awọn ọmọ Ibo lọhun-un, bo tilẹ jẹ pe ariwo ti awọn eeyan agbegbe naa n pa ni pe awọn gan-an lọrọ kan bayii lati di aarẹ Naijiria lọdun 2023.