Tinubu ta ko aba Atiku pe ki wọn ṣafihan igbẹjọ eto aarẹ faraalu

Adewale Adeoye
Aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lorileede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ati ajọ eleto idibo Independent National Electoral Commission (INEC), ilẹ wa, ti ta ko aba Alaaji Atiku Abubarkar, toun naa dije dupo aarẹ orileede yii, pe ki wọn ṣafihan gbogbo bi eto igbẹjọ ibo aarẹ ṣe n lọ nile-ejọ naa fawọn araalu lati maa fọkan ba a lọ.
Awọn mejeeji yii ni ọgbọn ati maa fa igbẹjọ naa gun kọja bo ṣe yẹ lohun ti Atiku n beere fun yii, eyi ko si ba ofin ilẹ wa mu rara. Paapaa ju lọ nigba ti ileejọ ilẹ wa ki i ṣe ibi igbafẹ tawọn eeyan yoo ti maa woran ohun gbogbo to n lọ lode.
Bẹẹ o ba gbagbe, Alhaji Atiku ati ẹgbẹ PDP ni wọn rọ ile-ejọ Tiraibuna kan niluu Abuja to n gbọ ẹjọ to su yọ lori esi ibo ti ajọ INEC ṣeto rẹ lorileede, eyi to waye ninu oṣu Keji, ọdun yii, ti wọn si n sọ pe ki wọn faaye gba awọn oniroyin lati maa ṣafihan bi igbẹjọ naa ṣe n lọ nile-ẹjọ ni gbara ti igbẹjọ naa ba ti bẹrẹ ni pẹrẹu
Ṣugbọn Tinubu ati ajọ INEC ti pẹjọ kan lati ta ko aba naa bayii. Wọn ni ki i ṣohun to daa rara, ki kootu ma si dahun si ohun ti Atiku n beere fun yẹn rara.
Atẹjade pataki kan lati ọwọ Wọle Ọlanipẹkun SAN, to n ṣoju ikọ awọn lọọya gbogbo ti Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu gbe iṣẹ naa fun sọ pe ohun ti ọgbọn tí Atiku fẹẹ da ni lati dari ẹjọ to pe naa sibomiiran pẹlu bo ṣe ni ki wọn faaye gba awọn oniroyin ki wọn maa ṣafihan bi igbẹjọ naa ṣe n lọ faraye ri.
O fi kun un pe ile-ẹjọ naa nikan lo laṣẹ lati mọ boya ohun ti Alaaji Atiku n beere fun yii wa ni ilana ati ibamu ofin to n gbọ ẹjọ naa.
Wọn ni ko sẹni ti ko mo pe ki i ṣe gbogbo ẹjọ lo yẹ kawọn araalu mọ ilana ti wọn gba daa rara.
O waa rọ awọn alaṣẹ ile-ejọ naa pe ki wọn ṣohun gbogbo ni ilana ti ko fi ni i tabuku kankan ba ile-ejọ, ki wọn sì má ṣe fakoko ṣofo rara lori ẹjọ ti Atiku pe naa.
Bẹ o ba gbagbe, Alaaji Atiku lo rọ ile-ejọ to n gbọ ẹjo to su yọ ninu eto idibo aarẹ ti wọn di nilẹ wa lọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Keji, odun yii, pe ki won faaye gba awọn oniroyin gbogbo lati maa gbe bi igbẹjọ naa ṣe n lọ sori afẹfẹ fawọn araalu lati mọ bi ohun gbogbo ṣe n lọ nile-ejọ naa.

Leave a Reply