Faith Adebọla
Bi ko ba si ayipada mi-in, aarẹ ati igbakeji aarẹ to jẹ ẹlẹsin kan naa, ẹlẹsin Musulumi, ni yoo bọ sori aleefa ti Oloye Bọla Ahmed Tinubu, oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ba jawe olubori ninu eto idibo to n bọ ni 2023.
Eyi ko ṣẹyin bi ọrẹ imulẹ Tinubu kan, Gomina ipinlẹ Kano, Umar Abdullahi Ganduje ṣe, la a mọlẹ pe awọn alẹnulọrọ ti ba Tinubu sọrọ, wọn ti gba a lamọran, o si ti gba si wọn lẹnu, pe igbakeji aarẹ ẹlẹsin Musulumi bii toun loun maa fa kalẹ, ti awọn yoo si jọ dije.
Ganduje sọrọ yii lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Keje yii, niluu Kano, lasiko to n ba awọn aṣaaju ẹsin Musulumi kan sọrọ nile ijọba ipinlẹ Kano, gẹgẹ bii apa kan ayẹyẹ ti wọn fi sami si ọdun Ileya ti ọdun yii.
O ni: “A ti gba a lamọran pe ẹlẹsin Musulumi ni ko fi ṣe igbakeji ara ẹ, o si ti gba si wa lẹnu. Tori naa, aarẹ ẹlẹsin Musulumi, igbakeji aarẹ ẹlẹsin Musulumi maa waye ni Naijiria. Eyi ki i ṣe tuntun, eyi kọ lakọọkọ,” gẹgẹ bo ṣe wi.
Lẹyin eyi lo ni kawọn alaafaa maa rọjo adura fun Tinubu, ko le kẹsẹ jari ninu erongba rẹ.
Tẹ o ba gbagbe, Tinubu ti kọkọ yan ẹlẹsin Musulumi kan gẹgẹ bii igbakeji, Alaaji Kabiru Masari, lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹfa, ṣugbọn o ni fidi-hẹ lasan ni, oun ṣi maa paarọ ẹ ki asiko too lọ.
Amọ, leralera ni ẹgbẹ awọn ẹlẹsin Kristẹni, Christian Association of Nigeria, (CAN) ti n ṣekilọ lodi si yiyan aarẹ ati igbakeji ẹlẹsin kan naa.
Ẹgbẹ naa sọ ninu atẹjade kan pe: “Ẹgbẹ oṣelu to ba gbiyanju lati yan aarẹ ati igbakeji ti wọn jẹ ẹlẹsin kan naa maa fidi rẹmi ni. Ọdun 1993 kọ la wa yii o. Nigba ti aarẹ ati igbakeji ẹ n ṣe ẹsin to yatọ sira, a ṣi mọ ohun ti oju awa Kirisitẹni ri. Ọlọrun nikan lo mọ iye Kirisitẹni ti wọn ti fẹmi wọn ṣofo laarin ọdun meje sẹyin, ti ko sẹni to wi nnkan kan, ko si ṣeni to mu wọn tabi ba wọn ṣẹjọ. Ẹ waa fọkan yaworan bi ọrọ naa ṣe maa buru to tawọn adari ba lọọ jẹ ẹlẹsin kan naa. Awọn ofin to ṣegbe lẹyin iwe ofin wa sọ pe imudọgba gbọdọ wa ni.”
Ireti wa pe Tinubu yoo kede ẹni ti igbakeji rẹ tuntun yoo jẹ lẹyin to de lati irinajo rẹ sorileede France laipẹ yii.