Tiriliọnu kan ati diẹ ni ipinlẹ Eko yoo na lọdun to n bọ fun iṣẹ ilu

Faith Adebola, Eko

Gẹgẹ bawọn gomina ṣe maa n ṣe lọdọọdun, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ti ka aba eto iṣuna ọdun 2021 fawọn aṣofin ipinlẹ naa, lẹyin eyi to gbe iwe aba to pe akọle ẹ ni ‘Bọjẹẹti Ireti Ọtun’ naa kalẹ siwaju wọn fun ayẹwo ati ibuwọlu wọn.

Apapọ owo ti iye rẹ jẹ tiriliọnu kan, aadọjọ miliọnu o le marun-un, okoolenirinwo o din meje naira (₦1,155,413,005,000.82) ni gomina ṣalaye pe wọn maa na ọdun to n bọ ọhun.

Lara owo yii, biliọnu mejidinlọgọfa aabọ naira (#118.36b) lo n lọ sori eto ilera, nigba ti eto ẹkọ maa nilo ọtalelogoje naira (#143.65b), biliọnu mejidinlogun aabọ (#18.31) pere ni wọn si fẹẹ na sori iṣẹ ọgbin. Ọrọ aabo maa nilo to biliọnu mejidinlogoji (#38.75b), iṣẹ ode atawọn nnkan amayedẹrun yoo gba ejidinlaaadọfa biliọnu naira (#108b), nigba ti eto imọ ijinlẹ ati ẹrọ igbalode yoo nilo biliọnu mejidinlọgbọn  (#28.2b) naira.

Sanwo-Olu ni ko digba teeyan ba gboye imọ nipa ọrọ aje ko too ri akoba nla ti itankalẹ arun korona ati rogbodiyan ta ko SARS ṣe fun ọrọ aje nipinlẹ Eko. Ohun to ju ida mẹrinlelogun ninu ọgọrun-un owo to yẹ kijọba pa wọle ni ko ṣee ṣe, eyi lo si fa a to fi jẹ pe pẹlu gbogbo ọgbọn tawọn da, agbara kaka lawọn fi doju ami ida mẹrinlelaaadọta ninu ọgọrun-un imuṣẹ bọjẹẹti ti ọdun yii.

O ni asiko tijọba iba tun tẹsiwaju, tawọn ti fẹẹ de ida ọgọrin ninu ọgọrun-un bọjẹẹti 2020 ọhun ni rogbodiyan iwọde ta ko SARS tun ṣẹlẹ, ti eyi si fa ọwọ aago sẹyin gan-an.

Sibẹ, gomina ni kawọn olugbe ilu Eko lọọ fọkan balẹ, tori gbogbo ọna nijọba oun maa ṣan lati ri i pe atunṣe de ba awọn ohun to bajẹ, ti igbe aye irọrun yoo si tubọ to tewe-tagba lọwọ nipinlẹ naa.

Ọpọ awọn eeyan ja-n-kanja-n-kan nipinlẹ Eko lo peju si ile apero awọn aṣofin nibi ayẹyẹ kika abadofin isuna naa n waye.

 

Leave a Reply