Tọkọ-taya lọọ ji ọkan ninu awọn ibeji gbe lọsibitu, wọn lawọn n wa ọmọkunrin dandan

Ti o ba jẹ pe aṣiri tu, diẹ lo ku kawọn tọkọ-taya ọran yii sọ idunnu baba atiya ibeji kan di ibanujẹ ayeraye, pẹlu bi wọn ṣe foru boju lọọ ji ọkan lara awọn ibeji oojọ lọsibitu ti wọn tẹ wọn si, ni wọn ba dana ariya rẹpẹtẹ, wọn n sọ faye pe awọn ti bi ọmọkunrin tuntun.

Abubakar Sadiq, ẹni aadọta ọdun, oun ati iyawo rẹ, Mariam Sadiq, ẹni ọdun mejilelogun, ti wọn n gbe Rijiya Zari Quaters, nijọba ibilẹ Ungogo, nipinlẹ Kano, ni wọn yọ kẹlẹ lọọ ji ọmọ ikoko kan to jẹ ọmọkunrin ninu awọn ibeji kan ni nnkan bii aago kan aabọ oru ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii.

Alaye ti DSP Abdullahi Haruna Kiyawa to jẹ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano ṣe lori iṣẹlẹ yii ni pe alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee to kọja, ni Ọlọrun fi awọn ejirẹ ta iya ikoko naa, Hajiya Fatimah Mohammad ati ọkọ rẹ Rabiu Mohammad, lọrẹ, ọsibitu ẹkọṣẹ iṣẹgun, Mohammad Abdullahi Wase Teaching Hospital, ni wọn bimọ ọhun si, niluu Kano.

Ṣugbọn ni nnkan bii aago mẹta aabọ oru ọjọ Satide ni Ọgbẹni Rabiu sare de teṣan ọlọpaa Kano jannajanna, lo n kigbe pe ọkan lara awọn ibeji tiyawo oun ṣẹṣẹ bi ti dawati lọsibitu o, kawọn ọlọpaa gba oun, ẹnikan ti ji oun lọmọ gbe lọ.

Wọn lo ṣalaye pe iya ikoko naa ṣi n sun oorun asunwọra lẹyin itọju ti wọn fun un, aburo rẹ obinrin, Rukyat, ni wọn fi ṣọ awọn ibeji naa ni wọọdu ti wọn tẹ wọn si, ṣugbọn oorun gbe aburo ọhun lọ nigba to ya, bẹẹ baba ọmọ ko si nitosi, o lowo tawọn fẹẹ san lọsibitu loun ṣaajo ẹ lọ. Igba ti Rukayat taji lo ri i pe ọmọ meji ti ku ẹyọ kan.

Awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ko sọrọ yii, wọn bẹrẹ si i wa ọmọ ikoko kiri, wọn o si ri i titi di irọlẹ ọjọ Satide naa. Ṣugbọn wọn ni olobo kan lo ta wọn nigba ti wọn gburoo ariwo ariya kan laduugbo ti Sadiq n gbe, aṣe awọn ni wọn tẹ pẹpẹ ariya, wọn lawọn bimọ tuntun, ọmọkunrin tawọn ti n wa latọjọ yii, lawọn eeyan ba n ba wọn jo, wọn n ba wọn yọ.

Nigba tawọn ọlọpaa de’bẹ lalẹ ọjọ Abamẹta naa laṣiiri tu, gbogbo ibeere ti wọn n bi tọkọ-taya ajọmọgbe yii, wọn o ri esi gidi fun wọn, niyawo ba jẹwọ ki wọn ṣe oun jẹẹjẹ ni toun, oun o bimọ o, pe niṣe lawọn ji ọmọ naa gbe lọsibitu ti wọn tẹ ẹ si.

Ki lo mu ki wọn ṣe bẹẹ? Ọlọpaa beere. Obinrin naa ṣalaye pe ọkọ oun lo fa a, o ni awọn ti bi awọn ọmọbinrin ṣugbọn ko sọkunrin ninu wọn, ẹkun ọmọkunrin si lọkọ oun n sun lojoojumọ, oun naa lo sin oun lọọ sọsibitu laajin oru tawọn fi lọọ ji ọmọ ọlọmọ gbe yii, o lọkọ oun lo n wa ọmọkunrin lọran-anyan o.

Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa ti paṣẹ ki wọn da ọmọ pada fọlọmọ, ibeji si ti pada sọdọ ekeji ẹ. Ni ti Maryam ati Abubakar yii, wọn niwadii ṣi n lọ lori ọrọ wọn, ṣugbọn ile-ẹjọ ni wọn maa balẹ si laipẹ.

Leave a Reply