Tọmọde tagba lo ṣẹyẹ ikẹyin fun agba oṣere ilẹ wa, Jimọh Aliu, to wọ kaa ilẹ lọ

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

O ti di ootọ gedegbe bayii, ko si si ani-ani mọ pe gbajugbaja agba-ọjẹ onitiata nni, Ọlajide Iṣọla Jimoh Aliu tawọn eeyan tun mọ si Aworo, ti wọ kaa ilẹ lọ nigba to ku bii oṣu kan aabọ ko pe ẹni ọdun mẹrindinlaaadọrun-un (86) laye gẹgẹ bii akọsilẹ.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, ni baba naa dagbere faye nileewosan ẹkọsẹ Fasiti Ekiti to wa niluu Ado-Ekiti, lẹyin naa ni wọn si gbe e lọ sile rẹ to wa ni adugbo Jimoh Aliu, lagbegbe Adebayọ, niluu kan naa.

Lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, ni wọn gbe e lọ siluu abinibi ẹ ti i ṣe Okemẹsi Ekiti, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ekiti, Aago mẹta geerege ni wọn gbe e wọ ilu naa, nibi tawọn iyawo ile atawọn fijilante ti yẹ ẹ si.

Nigba to di aago mẹrin lawọn aafaa kirun si i lara, ki wọn too sin in sẹgbẹẹ iboji baba to bi i lọmọ.

Ero rẹpẹtẹ lo wa nibi isinku naa, bo tilẹ jẹ pe ofin itakete-sira-ẹni ṣi wa nipinlẹ Ekiti, eyi si fi bi awọn eeyan ṣe fẹran baba ọhun han.

Oriṣiiriṣii ere ori itage, fiimu agbelewo ati nnkan ibilẹ ni baba naa da si, to si gbe ṣe nigba aye ẹ, eyi ti ko ni i jẹ ki orukọ ẹ parẹ ninu itan laelae.

Diẹ lara awọn fiimu to ṣe to lokiki ni ‘Iku Jare Ẹda’, ‘Yanpan Yanrin’, ‘Arelu’, ‘Fọpomọyọ’ ati ‘Irinkerindo’.

Awọn nnkan ribiribi to ṣe nilẹ yii lo jẹ ki wọn fi oriṣiiriṣii oye da a lọla, lara rẹ si ni Member of the Federal Republic (MFR) tijọba apapọ fun un.

Lasiko ti iku pa oju ẹ de, ere kan to ṣagbatẹru ẹ to pe ni ‘Olowo Itẹ’ lo n ṣe lọwọ nipinlẹ Ekiti, eyi si ni akọkọ ninu ere aṣa marun-un to fẹẹ ṣe gẹgẹ bii eto to wa nilẹ.

Oriṣiiriṣii nnkan lawọn eeyan ti sọ nipa baba naa, ẹni ti ọpọ gba pe akanda ni.

Leave a Reply