Tori bi awọn akẹkọọ ṣe fipa ba ẹlẹgbẹ wọn lo pọ, ijọba ti ileewe Chrisland pa l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Ijọba ipinlẹ Eko ti fi agadagodo gbangba sẹnu ọna to wọ ọgba ileewe Chrisland, l’Erekuṣu Eko, latari ẹsun ifipa ba ni lo pọ to waye laarin awọn akẹkọọ naa lasiko irinajo wọn lọ si ilu Dubai.
Akẹkọọ-binrin ọmọọdun mẹwaa kan ni wọn lawọn ẹlẹgbẹ rẹ fipa ba lo pọ, ti wọn si ya fidio iwa palapala ọhun, fidio naa bi awọn eeyan ninu bo ṣe balẹ sori ẹrọ ayelujara.
Oluranlọwọ lori eto iroyin si Gomina Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Eko, Ọgbẹni Jubril A. Gawat, lo kede ipinnu ijọba lori ileewe ọhun lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin yii, lori ikanni ayelujara rẹ, o ni:
“Ọrọ ifipa ba ọmọde laṣepọ ti wọn lo waye laarin awọn akẹkọọ ileewe Chrisland nigba ti wọn lo siluu Dubai, lorileede United Arab Emirates, laipẹ yii, ti detiigbọ ijọba Eko.
“A fẹ kẹ ẹ mọ pe ijọba ti bẹrẹ iwadii to lọọrin lori ẹsun yii, gbogbo awọn ileeṣẹ ijọba tọrọ kan pata ni wọn ti bẹrẹ iṣẹ lori ẹ.
“Lori ọrọ yii, a maa pese itọju ilera ati amọran to yẹ fawọn tọrọ naa kan.
“A fẹẹ fẹyin araalu lọkan balẹ pe ọwọ dain-dain nijọba fi mu ọrọ aabo ati alaafia awọn ọmọde, paapaa lawọn ileewe to wọn ti n kọ awọn ogo wẹẹrẹ wa niwee, gbogbo eto idalẹkọọ to yẹ lati pese fun wọn la n ṣe.
“A tun fẹẹ fi anfaani yii ran gbogbo araalu leti pe ẹnikẹni to ba n wo tabi ṣajọpin fidio to ṣafihan iwa ifipabanilopọ ọmọde, ẹṣẹ nla ni tọhun n da labẹ ofin, ẹwọn ọdun mẹrinla gbako lo fi n runmu.
“Eyi kan ṣiṣe atunṣe, atunya, gbigba, fifi ṣọwọ, tabi pinpin fidio naa kiri, ibaa jẹ lori ẹrọ ayelujara tabi lojukoju.
“Ni bayii na, gbogbo ileewe Chrisland to wa nipinlẹ Eko la ti ti pa, titi iwadii yoo fi pari.”

Leave a Reply