Tori Korona, ijọba apapọ tun da ofin konilegbele pada

Faith Adebọla

Pẹlu bi arun Koronafairọọsi tun ṣe n lagbara si i lawọn orileede agbaye kan lẹnu ọjọ mẹta yii, ijọba apapọ ti kede pe bẹrẹ lati oru ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, ofin konilegbele ti tun bẹrẹ jake-jado orileede yii.

Oluṣekokaari ọrọ pajawiri lori arun Korona, Ọgbẹni Mukhtar Mohammed, lo sọ ọrọ yii di mimọ lọjọ Aje, Mọnde yii, niluu Abuja, nigba to n sọ ibi ti iṣẹ de lori arun buruku ọhun fawọn oniroyin l’Abuja.

O ni lati ọjọ Tusidee, ofin konilegbele yoo wa lẹnu iṣẹ laarin aago mejila oru si aago mẹrin idaji.

Bakan naa lo ni ijọba ti paṣẹ pe kawọn ile faaji, ile ti won ti n sere idaraya (gyms), gbọngan ariya, atawọn ibi igbafẹ tero maa n pọ si wa ni titi pa lasiko yii na, ki ijọba fi wo bi itankalẹ arun yii ṣe n lọ si nilẹ wa ati kari aye.

Awọn ileejọsin gbogbo, ibaa jẹ ṣọọṣi tabi mọṣalaṣi ko gbọdo gba ju idaji iye ero ti wọn ti maa n gba tẹlẹ lọ.

O ni ijọba ko ni i fojuure wo ẹnikẹni to ba tapa sawọn aṣẹ yii, kawọn eeyan si ranti pe ofin Korona ṣi wa nilẹ pẹlu awọn ijiya ti wọn to sabẹ ẹṣẹ kọọkan.

Amọ ṣa o, awọn ti ọrọ wọn jẹ mọ akanṣe iṣẹ bii awọn oniroyin, awọn onitọju iṣegun atawọn agbofinro lanfaani lari jade fun  iṣẹ wọn, bo tilẹ jẹ pe awọn naa gbọdọ pa awọn alakalẹ to rọ mọ arun Korona yii mọ.

Leave a Reply