Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun idibo Guusu Ekiti, Biọdun Olujimi, ti sọ pe ko si ọna abayọ kankan ju ki gomina Ekiti tẹlẹ, Ayọdele Fayoṣe, gba awọn ti ipo tọ si laaye lati ṣiṣẹ fun idagbasoke ẹgbẹ People’s Democratic Party (PDP), paapaa nipinlẹ naa ati nilẹ Yoruba lapapọ.
Eyi ni ọrọ ti Olujimi n tẹnumọ lopin ọsẹ to kọja nigba to n sọrọ nipa aawọ to wa laarin oun ati Fayoṣe.
Sẹneto to ṣe oludamọran pataki fun Fayoṣe ni saa akọkọ fun ọkunrin oloṣelu naa tun ṣe igbakeji gomina fun un, eyi to tumọ si pe wọn ti jọ n bọ tipẹ, ajọṣepọ wọn si ti kọja ọdun mẹẹẹdogun.
Ọjọ keje, oṣu kẹta, ọdun yii, ni eto ibo PDP fawọn oloye wọọdu waye, ibẹ gan-an si ni ipinya manigbagbe ti waye laarin awọn mejeeji.
Lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu to kọja, ni igun mejeeji tun ṣe ibo ọtọọtọ fawọn oloye nijọba ibilẹ mẹridinlogun to wa nipinlẹ Ekiti, nigba to si di ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu to kọja, ni wọn tun yan awọn oloye ipinlẹ ọtọọtọ. Ọnarebu Bisi Kọlawọle di alaga igun Fayoṣe, nigba Ọnarebu Kẹhinde Ọdẹbunmi di alaga igun Olujimi.
Ọjọbọ, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, nija naa tun gba ọna mi-in yọ nigba ti Fayọse sọrọ si Gomina Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ nibi ipade kan to waye niluu Abẹokuta pe ko ma wa si Ekiti nitori oun yoo doju ija kọ ọ.
Lọjọ Ẹti, ọsẹ to kọja, ni lẹta kan to ni orukọ olu-ile ẹgbẹ naa l’Abuja jade, ninu eyi ti wọn ti fontẹ lu iyansipo Ọnarebu Bisi Kọlawọle, ṣugbọn igun Olujimi ni ayederu ni, awọn tawọn n ba ja lo tun n gbọna ẹburu yọ.
Lori rogbodiyan yii ati bi nnkan ṣe n lọ, eyi lawọn nnkan ti Olujimi sọ fun akọroyin wa:
Ajọṣepọ lati ibẹrẹ
Gbogbo awọn ti Fayoṣe ti ṣanfaani fun, mo ba wọn yọ, mo ba ara mi naa yọ, nitori mo wa lara wọn. Ṣugbọn ẹni to ba ṣoore fun ẹ to ba loṣoo ti i, o sọ ara ẹ di Ọlọrun niyẹn. Teeyan ba ṣoore fun ẹ to ro pe oun aa maa fohun silẹ fun ẹ ni gbogbo igba to ro pe o fẹẹ ṣe nnkan daadaa, Ọlọrun aa da ẹjọ. Igba ti o fi iwa yẹn han ni wahala too bẹrẹ.
Nnkan to fa rogbodiyan
Ko sija ta a ba Fayoṣe ja ju pe ko jẹ kawa naa ṣakoso tiwa. Ọlọrun ti fun un ni tiẹ, o ti se e, awa naa t’Ọlọrun fi sibẹ lasiko yii, ko gbaruku ti wa, iyẹn lo da wahala silẹ.
Ko sẹni to n ba Fayoṣe ja, oun lo n ba ara ẹ jẹ. Idi ni pe teeyan ba ti wa nipo kan to ba ti ṣe tiẹ, ko gbọdọ di ibẹ mọ awọn mi-in, Ọlọrun nikan lo n jẹ ‘afemi’. Ti eeyan kan ba ti sọ pe oun loun ni ẹgbẹ, ti ki i ṣe pe o fa wa ni tẹ̀ẹ̀tẹ́ wọ ọ ni, gbogbo wa la jọ wọ ọ, ko le maa fọwọ lalẹ fun wa.
Teeyan kan ba sọ pe gbogbo awa ta a wa ni igun yii, a ko jẹ eeyan, koun naa lọọ yẹ ara ẹ wo.
Ọrọ igun meji to wa l’Ekiti
Ọnarebu Kẹhinde Ọdẹbunmi atawọn oloye to ku la yan nilana ofin, wọn si ti n ba eto lọ lati gbe PDP goke agba. A nigbagbọ pe awa la maa leke nigbẹyin, Ọlọrun a dẹ fun wa ṣe.
Ija Fayoṣe ati Makinde
Mo dupẹ lọwọ awọn adari wa tuntun l’Ekiti fun bi wọn ṣe fọwọ si Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde gẹgẹ bii adari wa nilẹ Yoruba, eyi daa pupọ.
Ọrọ Ṣeyi Makinde ko le rara. Oun nikan ni gomina to jẹ ọmọ ẹgbẹ wa nilẹ Yoruba, o si ni imọ, oye ati ifẹ eeyan lọkan, bẹẹ lo gbọn gidi. Oun lo yẹ ko jẹ aṣoju wa patapata.
Iru igbesẹ yii naa la gbe nigba ti gomina tẹlẹ l’Ekiti, Ayọdele Fayoṣe, wa lori aleefa, nitori oun nikan ni gomina ẹgbẹ PDP nilẹ Yoruba nigba yẹn, a dẹ gbaruku ti i.
Mo ranti pe nigba yẹn, ipinlẹ Ọyọ ni iru wahala ta a ni l’Ekiti yii, Fayoṣe dẹ gbiyanju lati yan igbimọ alakooso le wọn lori. Iru ẹ naa tun waye lọpọ igba ni Eko ati Oṣun. O waa jẹ iyalẹnu pe ọrọ adari ẹgbẹ nilẹ Yoruba di ariyanjiyan bayii.
Ẹni to ba wa nibẹ lo n ṣe ibẹ. Ayọ Fayoṣe jẹ ọkan lara awọn adari PDP l’Ekiti, ṣugbọn ko le sọ pe oun n du ipo adari ilẹ Yoruba.
Bi Fayoṣe ṣe ko awọn kan lọọ ṣepade ni Abẹokuta gan-an ko tọna nitori Ọlọrun ti fi olurọpo sẹyin gbogbo ẹda, asiko ti Gomina Makinde lo kan.
Ko si nnkan ti Makinde ṣe ju pe o ni ẹni kan ko le gba Ekiti la, o ni ki n duro digba ti ọrọ yii maa niyanju, ti gbogbo wa maa pada jẹ ọkan, nnkan to sọ to fi jẹbi niyẹn o.
Gbogbo ẹnu la fi sọ ọ pe ki Makinde maa bọ l’Ekiti, a maa ṣajọyọ ẹ, ihalẹ lasan ni pe ko ma wa.
Igbesẹ awọn adari ẹgbẹ patapata
Gbogbo eleyii to n waye yii n tẹsiwaju nitori awọn adari ẹgbẹ lapapọ n ṣatilẹyin fun Fayoṣe. Asiko ti to fun wọn lati kede atilẹyin wọn fun gomina tẹlẹ, iyẹn Fayoṣe, tabi adari ilẹ Yoruba to jẹ gomina to wa lori alaeefa lọwọlọwọ.
Ti wọn ko ba rọra le maaluu to ja wọ ìsọ̀ àwo yii, a maa ran onisọ lọwọ lati le e jade. Ki gbogbo eeyan yaa mọ pe a mọ nnkan ta a n ṣe, ti ẹgbẹ yii ko ba si ṣatilẹyin fun ida ọgọrin to wa lọdọ tiwa, a maa jọ wọn loju. O to gẹẹ.
Fayoṣe ko le gba awọn nnkan to n ṣe yii laelae. Ki lo de tawọn adari n gba a laaye lati jẹ gaba lori ẹgbẹ wa? Abi nnkan kan wa ti a ko mọ nipa ọrọ yii ni? Ṣe wọn fẹẹ tọju ẹgbẹ ni, abi wọn fẹẹ tọju eeyan kan?
Igbesẹ alaafia lori ọrọ yii
Fayoṣe ni ko jẹ ki igbimọ to fẹẹ ṣiṣẹ yẹn l’Ekiti ṣiṣẹ nitori igba meji pere ni wọn ṣepade, o si fagidi mu wọn lati ṣe nnkan to fẹ.
To ba jẹ pe awọn adari wa ko gbọ ẹjọ ẹni kan da ni, wọn ti maa pe gbogbo wa, a ti maa jokoo, a ti maa ri ọna abayọ.
Ọna abayọ
Ẹ jẹ ko wa ninu akọsilẹ pe a ko ni i gba ọkunrin to ṣakoba nla fun wa lasiko ta a fi omi ati ẹjẹ ara wa jiya laaye lati jẹ ka tun fidi-rẹmi.
Yẹyẹ ara wa ta a n ṣe nigboro jẹ kawọn eeyan ro pe oun lo ni ẹgbẹ. Ẹgbẹ gbọdọ gbe igbesẹ bayii tabi ki wọn kabaamọ.
A finu-findọ wọ inu ẹgbẹ yii ni, ko sẹni to mu wa wọle, ko si sẹni to maa halẹ mọ wa lati le wa lọ nitori a maa fi ẹjẹ wa silẹ.
Ti wọn ko ba gba wa laaye lati ṣeto ẹgbẹ yii lọna to ba ofin mu ta a fẹẹ tọ, ija ṣẹṣẹ bẹrẹ ni.