Wahala n bọ o, Makinde ati Fayoṣe fẹẹ gbena woju ara wọn

Adefunkẹ Adebiyi, Ogun

Bi awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu PDP ko ba tete wa nnkan ṣe si i, afaimọ ki ija agba to n lọ laarin Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ati gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayọdele Fayoṣe ma ṣakoba nla fun ẹgbẹ naa. Eyi ko sẹyin bi Fayọṣe ṣe n kilọ fun gomina Ọyọ naa pe ko ma da si ohun to n lọ nipinlẹ oun.

Ọjọbọ, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni Fayọse sọrọ naa niluu Abeọkuta, nipinlẹ Ogun, nibi ipade to waye lati fẹnu ko lori ẹni ti wọn yoo fa kalẹ gẹge bii igbakeji alaga fun ilẹ Yoruba ninu ibo ẹgbẹ naa ti yoo waye laipẹ. Oun lo ko ko awọn aṣoju ẹgbẹ naa atawọn alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ekiti, Ọṣun ati Eko sodi lọ si Abeokuta ti ipade naa ti waye.

Fayọse fi aidunu rẹ han si bo ṣe ni Gomina Makinde n da si ọrọ to n lọ ninu ẹgbẹ naa lawọn ipinlẹ kaakiri. Gomina tẹlẹ yii ni bo tilẹ jẹ pe Makinde ni aṣaaju ẹgbẹ naa ni ilẹ Yoruba nitori ipo rẹ gẹgẹ bii gomina kan ṣoso ti ẹgbẹ naa ni nibẹ, o ni pẹlu rẹ naa, o gbọdọ fi akoso ẹgbẹ silẹ fawọn adari ipinlẹ kọọkan lati mojuto o ni. Ko ma tori ipo yii maa da si awọn ohun ti ko kan an.

Ọkunrin naa ni niṣe loun yoo ba Makinde kẹsẹ bọ sokoto kan naa to ba wa sipinlẹ Ekiti waa paṣẹ onikumọ kan.

Fayọṣe ni, ‘Pe o jẹ gomina ko sọ pe ki o waa maa da si ohun to n lọ nipinlẹ mi-in. Keeyan ma wa si ipinlẹ temi o, bo ba wa si ipinlẹ mi, ma a doju ija kọ ọ gidi. Ṣugbọn ma a tẹsiwaju lati maa bu ọla fun un nitori arakunrin mi ni, mo si nifẹẹ rẹ daadaa, emi naa wa ninu awọn to ṣagbara lati gbe e wọle sipo gomina.

One thought on “Wahala n bọ o, Makinde ati Fayoṣe fẹẹ gbena woju ara wọn

Leave a Reply