Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn alaṣẹ ileewe Obafemi Awolowo University, Ile-Ifẹ, ti kilọ fun gbogbo awọn eeyan Ifẹ ti wọn kọle sori ilẹ ileewe naa lati gbe e kuro nibẹ ko too di pe awọn yoo bẹrẹ si i wo o funra awọn.
Ninu ipade oniroyin kan ni ọga agba ile-ẹkọ giga naa, Ọjọgbọn Eyitọpẹ Ogunbọdẹde, ti sọ pe awọn eeyan kan ti n wọnu ilẹ awọn lagbegbe Parakin, niluu Ileefẹ.
Gẹgẹ bo ṣe wi, eeka ilẹ to din diẹ ni ẹgbẹrun mejila lo jẹ ti ileewe naa lati ọdun 1961, ṣugbọn ṣe ni awọn kan deede dide, ti wọn sọ pe ilẹ ti awọn baba-nla awọn niluu Ileefẹ fun awọn ti pọ ju, ki awọn yọnda abala to wa lagbegbe Parakin.
Gẹgẹ bi Ogunbọdẹde ṣe wi, “Awada la kọkọ pe ọrọ naa, afigba ti wọn bẹrẹ si i kọle sori ilẹ wa, koda, wọn tun bẹrẹ si i ta a fawọn ẹlomi-in. Awa alaṣẹ lọ sọdọ Ọọni Adeyẹye Ogunwusi to jẹ alaga igbimọ alamoojuto ileewe wa, bẹẹ la ṣepade pẹlu awọn adari ilu Ileefẹ, sibẹ, ko so eso kankan.
“Idi niyi ti a fi ro o pe asiko ti to lati gbe igbesẹ ofin lori ọrọ naa. Ijọba apapọ ati Minisita to n ri si eto ẹkọ lorileede yii, Mallam Adamu Adamu paṣẹ, pe ka ṣe ikede lori redio Ọṣun lati kilọ fun awọn ti wọn n huwa naa lati dẹkun ẹ.
“Ileewe wa ko ṣetan lati fi ilẹ kankan silẹ fun ẹnikẹni, ohunkohun ti ẹnikẹni ba si ti kọ sori rẹ, ki wọn tete gbe e kuro nitori a maa gbe igbesẹ akọkọ ti i ṣe mimọ fẹnsi yi gbogbo ilẹ wa ka.
“A ti ṣalaye gbogbo ẹ fun awọn agbofinro, ẹnikẹni to ba si tapa si aṣẹ yii, yoo da ara rẹ lẹbi”
Ṣugbọn nigba to n fesi si ọrọ naa, agbẹnusọ fun awọn eeyan Ifẹ, Banwo Ogundipẹ, sọ pe awawi lasan ni awọn alaṣẹ OAU n sọ, ati pe ṣe ni wọn kan fẹẹ fi ọrọ didun fa oju awọn alaimọkan mọra lori ọrọ ilẹ ọhun.
O ni ki wọn mu aworan ilẹ naa (map), jade, ninu eyi ti wọn ti le fọwọ sọya pe ilẹ Parakin wa lara ilẹ ti wọn fun ileewe naa lọdun 1961. O fi kun ọrọ rẹ pe aworan kan ti wọn ya funra wọn lọdun 1987 ni wọn n gbe kaakiri, ati pe ti ọrọ naa ba da wọn loju, ṣe ni ki wọn gbale-ẹjọ lọ.