Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Igun kan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun ti wọn jẹ ti Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti fẹhonu han niluu Oṣogbo l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, wọn ni gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, ti n da sọrọ to n lọ laarin awọn l’Ọṣun ju.
Awọn olufẹhonuhan ọhun ni wọn gbe oriṣiiriṣii akọle dani. Lara ohun ti wọn kọ sibẹ ni “Seyi Makinde, jọwọ, ma ṣe da si ọrọ ẹgbẹ PDP Ọṣun mọ.” “Fun awọn alakooso apapọ ẹgbẹ wa lanfaani lati ṣiṣẹ wọn.”, “Aja ki i roro ko ṣọ ojule meji” ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Wọn ni idi pataki tawọn fi n fẹhonuhan ni bi awọn igbimọ ti awọn adari ẹgbẹ naa ran wa lati Abuja lati ṣeto idibo wọọdu wọn ṣe kede pe awọn sun ọjọ idibo naa ṣiwaju.
Adari awọn to n fẹhonu han ọhun, Dokita Lere Oyewumi, sọ pe nigba tawọn beere lọwọ awọn ọmọ igbimọ ọhun pe ki lo de ti wọn ko tẹsiwaju ninu idibo ọhun, ṣe ni wọn sọ pe aṣẹ ti awọn gba lati sẹkiteriati ẹgbẹ ni pe ki awọn dawọ duro latari abajade idajọ kootu kan.
Oyewumi kilọ pe Gomina Makinde ati gomina ipinlẹ Adamawa, Fintiri, ko gbọdọ da sọrọ to ba ti ni i ṣe pẹlu ẹgbẹ PDP Ọṣun mọ, nitori awọn mọ pe Makinde lo wa lẹyin bi wọn ṣe da idibo naa duro.
O ni awọn ti yan ọmọ ẹgbẹ mẹtalelaaadọrun-un lati gbogbo ijọba ibilẹ to wa l’Ọṣun. “Awọn igbimọ yẹn ti de pẹlu awọn adari wa marun-un to yẹ ki wọn ṣeto idibo, ṣugbọn ṣe ni wọn deede pe wa si otẹẹli kan, ti wọn si sọ pe awọn ko le ṣe idibo mọ latari iwe kootu kan ti wọn gba.
“Nigba ti a ba awọn kan sọrọ l’Abuja, o di mimọ pe awọn alaṣẹ apapọ ẹgbẹ wa kọ ni wọn paṣẹ yẹn. Alẹ la too pada gbọ pe awọn alaṣẹ ṣepade, ti wọn si sọ pe ki wọn sun idibo naa siwaju. O da wa loju pe awọn kan wa ninu ẹgbẹ PDP ti wọn ko fẹ ki ẹgbẹ yii rọwọ mu l’Ọṣun.
“A ko fẹẹ ri eyikeyii lara awọn ọmọ igbimọ ti wọn ran wa tẹlẹ nibi lọjọ Sannde, ti a ba foju kan wọn nibi, awọn kọ ni wọn aa duro sọ itan rẹ. Awọn eeyan mi-in ni ki wọn ran wa.”
Lẹyin igba yẹn ni Oyewumi fi lẹta ifẹhonuhan wọn, eleyii ti wọn kọ si awọn alaṣẹ apapọ ẹgbẹ naa, le alaga igun wọn, Sunday Bisi, lọwọ.