Florence Babaṣọla
Awọn ọrẹ mẹta kan; Tijani Wasiu, ẹni ọdun marundinlogoji, Akangbe Tairu, ẹni ọdun marundinlogoji ati Samad Mutairu, ẹni ọgbọn ọdun, ni wọn ti foju bale-ẹjọ Majisreeti ilu Oṣogbo lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii lori ẹsun meji.
Awọn olujẹjọ mẹtẹẹta ni wọn sọ pe wọn dawọ jọ lu ọba alaye kan, Alabudo ti Ibudo, nijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ, nipinlẹ Ọṣun, Ọba Mọrufudeen Ọlawale.
Agbefọba, Inspẹkitọ Kayọde Asanbe, ṣalaye fun kootu pe aago mẹrin irọlẹ ogunjọ, oṣu keji, ọdun yii, ni wọn lọ si abule Abudo, niluu Awo, nibẹ ni wọn si ti da wahala silẹ.
O ni ṣe ni wọn kọkọ lu awọn lebira ti wọn n ṣiṣẹ laafin naa lalubami, nigba ki Alabudo gan-an funra rẹ si yọju, igbaju-igbamu ni wọn fi pade kabiesi lọna, ti wọn si tun fi pẹtẹpẹtẹ ada na an.
Asanbe sọ siwaju pe iwa ti awọn olujẹjọ hu ni ijiya nla labẹ ipin ọjilenigba o le mẹsan-an (249) ati (351) ọtalelọọọdunrun o din mẹsan-an abala ikẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran ọdun 2002 tipinlẹ Ọṣun n lo.
Amọ ṣa, awọn olujẹjọ mẹtẹẹta sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti agbefọba fi kan wọn.
Agbẹjọro wọn, A. O. Okgi, rọ ile-ẹjọ lati fun wọn ni beeli nitori wọn ṣetan lati fi awọn oniduuro ti wọn lorukọ silẹ.
Ṣugbọn kia ni agbefọba ta ko ẹbẹ agbẹjọro awọn olujẹjọ, o ni, abuku ati arifin nla ni fun ẹnikẹni lati ṣiwọ soke lu ori-ade, ka too wa sọ pe ki wọn fi ada na an.
Majisreeti Iṣọla Omiṣade paṣẹ pe ki wọn lọọ fi awọn mẹtẹẹta pamọ sọgba ẹwọn titi di ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu keji, tidaajọ yoo waye lori beeli wọn.