Faith Adebọla
Ko sirọ ninu ọrọ ti Yoruba maa n sọ pe ‘iyawo dun lọṣingin,’ tabi owe to sọ pe ‘aṣẹṣẹgbẹ iyawo, bii tẹyin ki n pọn ẹ lo n ri,’ iru ayọ ati iriri rere yii lo ṣẹlẹ si gbajugbaja onkọrin Fuji ilẹ wa nni, Wasiu Ayinde Ọmọgbọlahan Anifowoṣe, tawọn eeyan mọ si Wasiu Ayinde Marshal tabi K1. Ṣinkin bii ẹni jẹ tẹtẹ oriire ni inu ọkunrin naa n dun.
Eyi ko ṣẹyin iyawo tuntun to ṣẹṣẹ wọle K1, bi ifẹ ṣe n rọjo lọdọ iyawo lọọdẹ ọkọ, bẹẹ ni Wasiu naa n fi adura ati ọrọ ifẹ didun fesi fun apọnbeporẹ rẹ yii.
Lori ikanni fesibuuku rẹ, ohun ti Wasiu kọ sibẹ ree:
“Oni lọjọ ayọ wa ti Ọlọrun ti ṣe, Oun lo pe wakati yii ni tiwa. Gbogbo ọrun lo n yọ, ẹyin eeyan ẹ ba wa yọ kẹ ẹ si yin Oluwa logo lori itẹ Ẹ.
”Saamu 118 ẹsẹ 24 sọ pe: “Eyi ni Ọjọ Oluwa, awa yoo si maa yọ ninu rẹ.” Bi a ṣe ji loju oorun lonii Ọjọruu, Wẹsidee kẹta ninu oṣu kọkanla yii, to jẹ ọjọ ti a maa so wa pọ, ti a maa dupẹ, ti a oo si yin Ọlọrun logo fun gbogbo oore to ti ṣe laye wa lati ibẹrẹ irinajo yii, inu wa dun.
”Ki Ọlọrun jẹ ki gbogbo ala rere wa ṣẹ. Ki Ọlọrun Olodumare ṣaanu fun wa, ka ri ojurere ati oore-ọfẹ ẹ gba, ka ri na, ka ri lo, ka si laluyọ, lorukọ Ọlọrun Ọba.
”Ọlọrun aa fẹsẹ wa mulẹ fun rere, yoo si pese fun wa, aa jogun ilera fun wa. Ọlọrun Josẹfu maa yi ero buruku awọn ọta ile ati tode pada si ibukun ailopin fun wa. Ko si ero ibi kan to ta ko ero Ọlọrun lori aye wa to maa wa si imuṣẹ.
”Ki la tun fẹẹ maa wi? Ti Ọlọrun ba ti wa fun wa, ta lo le lodi si wa (Roomu ori kẹjọ ẹsẹ kọkanlelọgbọn). Awọn ogun ọrun maa ja fun wa, wọn maa ṣẹgun gbogbo ogun ta a mọ ateyi ta o mọ to ba dojukọ wa. Alaafia Ọlọrun maa to tayọ gbogbo ero eeyan maa kun ọkan wa, yoo si wa pẹlu wa titi lae. Amin.
”Ajikẹ Ọkin mi, kaabọ sile o.’’
Ohun ti Wasiu Ayinde kọ ree. Latigba naa lawọn tiẹ ti n ki i ku oriire.