Willian balẹ si Arsenal lẹyin ọdun meje ni Chelsea

Oluyinka Soyemi

Agbabọọlu Chelsea tẹlẹ, Willian Borges da Silva, ti balẹ si Arsenal lẹyin to tọwọ bọ iwe adehun ọlọdun mẹta pẹlu kilọọbu tuntun ọhun.

Ẹni ọdun mejidinlọgbọn naa gbe igbesẹ yii lẹyin ọdun meje ni Chelsea, nigba ti idunaa-dura ko si wọ mọ lo kẹru ẹ.

Ọmọ ilẹ Brazil naa nireti wa pe yoo ran Arsenal lọwọ ni saa to n bọ pẹlu bi Mikel Arteta to jẹ kooṣi ṣe n ko awọn agbabọọlu jọ lati da kilọọbu naa pada sipo aṣaaju.

Ife-ẹyẹ Premier League meji, Europa League kan, FA Cup kan ati League Cup kan ni Willian gba lasiko to wa ni Chelsea, o si wa lara awọn ti ko ṣe e fọwọ rọ sẹyin ni kilọọbu ọhun.

Ọmọ ilẹ Brazil ni, bẹẹ lo gba bọọlu lawọn kilọọbu ilẹ naa, Ukraine ati Russia ko too balẹ si England lọdun 2013.

Ipele U20 ẹgbẹ agbabọọlu Brazil lo kọkọ wa ko too gba igbega lọdun 2011.

Leave a Reply