Laipẹ yii ni arun Koronafairọọsi kọlu Aarẹ orilẹ-ede America, Donald Trump, ati iyawo ẹ, Melania, kaakiri agbaye si ni wọn ti n ki i, ti wọn n ṣadura fun un wi pe aisan ọhun ko ni i mọna ẹmi.
Eyi naa ni Aarẹ Muhammed Buhari ṣe o, bo si ti gbe e sori ẹrọ abẹyẹfo rẹ, twitter, to ki Donald Trump, to si tun ṣadura fun un pe ki Ọlọrun tete mu un lara da, bẹẹ ni Wizkid naa gba ori ẹrọ abẹyẹfo rẹ, twitter lọ, nibẹ gan-an lo ti kan Aarẹ orilẹ-ede yii labuku. O kọ ọ sibẹ pe “Baba, ọrọ Donald Trump ko kan yin rara, awọn ọlọpaa atawọn ọtẹlẹmuyẹ Sars ti wọn n pa awọn ọdọ ni Naijiria lojoojumọ ni kẹ ẹ ba wa mojuto, ko sohun to kan yin ninu ọrọ America, orilẹ-ede tiyin ni kẹ ẹ kọju mọ.”
Bo ti ṣe kọ ọ niyẹn o, ohun tawọn eeyan si n sọ ni pe afaimọ ki ohun to ṣe yii ma di ọran si i lọrun, nitori ohun ti Buhari ṣe ki i ṣe ohun to buru rara. Wọn ni, kaakiri agbaye lawọn eeyan ti n ki Aarẹ Amẹrika, toun naa ba si ki i, eyi ko yẹ ko fa iru abuku bẹẹ.
Bakan naa lawon mi-in sọ pe ko si wahala ninu ki eeyan sọ ero ọkan ẹ, ohun ti Wizkid ṣe, ero ọkan ẹ lo gbe jade. Ati pe ẹtọ ọmọniyan paapaa faaye gba a daadaa labẹ ofin.
Buhari o ti kan abuku o si ma pada te ti yo fi ate tedi ni Nigeria yi. O ti su awa ara ilu patapata bayi.
Imoran lofun olori riwa kiwalofefa waala fun nibe
Erote mi Nile koye lasi waju gidi rara eni ti won fi se pe ni koye leni adura
Kosi ohun to buru ninu nkan to so yen ,ki ijoba naijiria bawa wa nkan se si ipaniyan L’ori lede yi ni ooooo
There is nothing bad about his comment,let the Nigerian government take a quick intervention to curb d unlawful killings that rampered every where today.
GOD BLESS NIGERIA
GOD BLESS US WE THE VOICELESS NIGERIANS
ONE NIGERIA WE MOVE FORWARD
Ko si ohun to buru ninu ohun ti Wizkid so, amoran lo gba ijoba buari kise abuku rara, eyin oniroyin yi ema fa wahala si omo olomo lorun
Kosi aburu ninu nkan ti odomode yii so rara sugbon ododo oro ni aare buhari kokin fe gboo.
Oun ti wizid so naa koitipoju tabani kawo dada imonran logba ARE orile edewa pe eje karan aso Nigeria wa na kato bawon ranti orile ede America