Wọn gun gende kan pa, ọpọ eeyan tun fara pa ninu ija igboro n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gende Ọlọrun kan lo fo ṣanlẹ to ku, nigba ti ọkẹ aimọye eeyan fara pa yannayanna ninu ija igboro to waye laarin awọn ọmọ iṣọta n’Ibadan lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja, la gbọ pe ija to le ku ọhun bẹ silẹ laduugbo Elekurọ, n’Ibadan, bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to mọ pato ohun to ṣokunfa ija igboro naa.

Awọn nnkan ija oloro bii ibọn ilewọ, ọbẹ, apola igi, oogun abẹnu-gongo atawọn nnkan mi-in lawọn ẹruuku ọhun fi doju ija kọra wọn laarin wakati mẹta ti ija ọun fi waye.

Aarẹ ẹgbẹ awọn ọdẹ ibilẹ ti wọn n pera wọn ni Sọludẹrọ Hunters Association, Ọba Wahab Ajijọlaanọbi, fidi ẹ mulẹ pe ọpọ eeeyan ni iba padanu ẹmi wọn sinu iṣẹlẹ yii bi ki i baa ṣe pe oun atawọn ọmọ ẹgbẹ oun tete lọọ pẹtu sija igboro naa.

O fidi ẹ mulẹ pe sibẹsibẹ, gende kan ti ṣubu loju ija nigba ti awọn fi maa debẹ. Ija ọhun si ti tàn de awọn adugbo bii Lábọ́, Orita-Aperin, Ọ̀rányàn, Wesley College l’Elekurọ, Kòsódò ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ija igboro nla gbaa ni. Awọn to doju ija kọra wọn ọhun to gende ọkunrin bii ẹẹdẹgbẹrin (700), o jọ pe wọn ranṣẹ pera wọn kaakiri awọn adugbo yooku nigboro Ibadan ni. Ẹni kan ṣubu loju ija yii, gigun ni wọn gun un lọbẹ pa si adugbo Kosodo.”

ALAROYE gbọ pe lati bii ọjọ mẹta kan lawọn ọmọ iṣọta naa ti n leri ija sira wọn ko too di pe kinni ọhun di ija igboro ti ko yatọ si bii igba ti awọn agbegbe bii mẹfa dide ogun sira wọn.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni awọn ọlọpaa, pẹlu iranlọwọ agbofinro ijọba ipinlẹ Ọyọ (Operation Burst), ti gbakoso eto aabo gbogbo agbegbe naa bayii, alaafia si ti jọba nibi gbogbo.

 

O lọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ ọkan ninu awọn janduku eeyan ti wọn fura si pe o lọwọ ninu rogbodiyan naa ati pe iwadii si n lọ lọwọ lati ri awọn yooku mu.

Leave a Reply