Wọn ṣi fila lori Fayoṣe l’Ondo, lo ba ni, ẹ ma pa mi bẹ ẹ ṣe pa Bọla Ige

Aderounmu Kazeem

Gomina Ipinlẹ Ekiti tẹlẹ Peter Ayọdele Fayoṣe ti pariwo sita wi pe kí awọn ọmọ Naijiria gba oun, nitori bí awọn eeyan kan ṣe ṣi fila lori ẹ nibi ìpolongo ibo tí ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe l’Ondo, l’Ọjọruu Wẹsidee to kọja yìí.
Bí iṣẹlẹ ọhun ṣe waye lọkunrin oloṣelu yii tí sọ pe oun mọ awọn eeyan to wa nídii ọrọ ọhun, o ni fila ti wọn sì lori oun lasiko toun fẹẹ gun itage lọọ darapọ mọ awọn oloṣelu yooku ko ṣadeede ṣẹlẹ, gomina ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Ṣeyí Makinde ati Bọde George ni wọn dẹ awọn ọmọọta soun.
Ọkunrin oloṣelu yìí waa sọrọ kan, o ni bi wọn ti ṣe ṣì fila lori Bọla Ige naa ree n’Ile Ifẹ, ko si pẹ si akoko naa rara, ti ọkunrin oloṣelu naa ṣe ku.

Oṣokomọlẹ gẹgẹ bi awọn ololufẹ ẹ ṣe maa n pe e ti sọ pe nitoun, oun ko nii fọwọ kekere mu iṣẹlẹ ọhun.
O ti sọ pe oun yoo fi to awọn agbofinro leti, ti igbimọ ẹgbẹ oṣelu PDP paapaa yoo gbọ si iṣẹlẹ ọhun, bẹẹ ni gbogbo aye yoo mọ pe awọn eeyan kan ti n lepa ẹmi oun kiri nínu ẹgbẹ.
Ogbẹni Lere Ọlayinka, ẹni tí ṣe oluranlọwọ fun un nípa eto iroyin ninu iwe to fọwọ sì sọ pe ọkunrin oloṣelu naa ko nii ye sọ ootọ ninu ẹgbẹ́, ati pe awọn eeyan kan ti wọn ko ri ohun rere kan ṣe fun ẹgbẹ naa lati ọdun 1999 l’Ekoo gbọdọ fẹyinti, gẹgẹ bi Oṣokomọlẹ ṣe wi, bo tilẹ jẹ pe níṣe lọrọ ọhun dun Bọde George atawọn eeyan ẹ gidigidi.
Fayoṣe fi kun un wi pe awọn to ṣi fila lori oun mọ ọn mọ fẹẹ fi yẹyẹ oun ni, ṣugbọn oun ko ni i fọwọ yẹpẹrẹ mu un ki wọn ma lọọ pa oun danu bi wọn ti ṣe ṣe fun Bola Ige, ati pe ti ohunkóhun ba sẹlẹ si oun lọdọ Bode George ati Seyi Makinde gomina wọn nipinlẹ Ọyọ ni ki gbogbo araye wa a si.

Leave a Reply