Wọn ṣi n wa awọn agbebọn to paayan mọkandinlogun, ti wọn tun dana sunle rẹpẹtẹ ni Katsina

Faith Adebọla

Titi di ba a ṣe n sọ yii, wọn ṣi n wa awọn agbebọn to paayan ti ko din ni mọkandinlogun tawọn janduku agbebọn ṣeku pa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, nigba ti wọn ya bo abule Tsauwa, nijọba ibilẹ Batsari, nipinlẹ Katsina, ipinlẹ ti wọn ti bi Aarẹ Muhammadu Buhari.

Ba a ṣe gbọ, nnkan bii aago mejila ọganjọ oru tawọn eeyan ti sun fọnfọn lawọn afẹmiṣofo naa de tibọn-tibọn sabule ọhun, ni wọn ba ṣina ibọn ibolẹ.

Ariwo ibọn yii lo ji awọn olugbe abule naa, pẹlu ibẹru ati ojora to ti mu wọn, niṣe ni kaluku n sa sẹnu ọta ibọn to n fo kaakiri.

Ọkan lara awọn olugbe abule naa tori ko yọ sọ pe awọn janduku yii tun yinbọn mọ awọn to n sa lọ sinu igbo paapaa, bẹẹ ni wọn n dana sun ile pẹlu ero lati sun awọn to ba kọ lati jade sẹnu ibọn mọle.

“Ibọn ba awọn mi-in, awọn kan si fara gbọgbẹ gidigidi, ṣugbọn nigba tilẹ mọ laaarọ ọjọ Tusidee, eeyan mọkandinlogun lo ti doloogbe loju-ẹsẹ.

Yatọ si ile gbigbe, awọn ọdaju apaayan yii tun dana sun awọn aba ati pẹpẹ tawọn eeyan n ko ounjẹ bii agbado, ẹwa, jeero ati ọka baba si, bẹẹ ni wọn ko awọn dukia ati ẹran ọsin bii aguntan ati ewurẹ wọn lọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn ti bẹrẹ iwadii nipa ẹ.

Leave a Reply