Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Lasiko ti a n kọ iroyin yii lọwọ, ko sẹni to ti i mọ orukọ, ile tabi ibi yoowu ti obinrin ti oku rẹ ti n jẹra yii ti wa. Ohun to kan daju ni pe inu igbo kan l’Oke-Mosan, l’Abẹokuta, ni awọn kan pa a si, ti wọn si ki okun bọ ọ lọrun, ti wọn jẹ ko da bii pe o pokunso ni.
Ọjọ Ẹti, ọgbọnjọ, oṣu kẹwaa, ni fọto yii jade sori ẹka ayelujara Fesibuuku. Obinrin ọlọpaa kan torukọ rẹ n jẹ Azeez Ọmọlẹwa Rasheedat, lo fi fọto naa sita lori ikanni rẹ, ohun to si kọ sibẹ ni pe awọn kan ti ẹnikẹni ko mọ lo pa oloogbe naa sinu igbo l’Oke-Mosan.
Ọlọpaa to wa nidii ẹjọ naa rọ awọn eeyan lati maa pin fọto naa kari ẹka ayelujara titi ti yoo fi de ọdọ awọn ẹbi oloogbe naa tabi awọn to mọ ọn.
Bakan naa lo fi kun un pe bi ẹnikẹni ba ni ohunkohun lati sọ tabi mọ nnkan kan nipa iṣẹlẹ iku obinrin yii to le ran ọlọpaa lọwọ, ki wọn kan si teṣan ọlọpaa Ibara, l’Abẹokuta. Tabi ki wọn pe nọmba yii:07076152560.