Wọn binu lu were pa l’Ọrẹ nitori ẹrọ ATM to bajẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Were kan lawọn eeyan binu lu pa niwaju banki kan niluu Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo, ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ Aje, Mọnde ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii.

ALAROYE gbọ latẹnu ẹnikan ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ pe ko sẹni to mọ iru ẹmi to ba le were naa lalẹ ọjọ ta a n sọrọ rẹ yii.

O ni ṣe lawọn eeyan sadeedee ri i to n ba awọn ẹrọ ATM ile-ifowopamọ banki kan to kọ lati darukọ rẹ fun wa jẹ.

Gbogbo akitiyan awọn to wa nitosi, paapaa awọn eeyan to fẹẹ gbowo ninu ẹrọ ATM naa lati da a duro lo ni o ja si pabo.

Ohun to ni o bi awọn eeyan kan ninu ree ti wọn fi suru bo o, ti wọn si lu u titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ.

O ni oku were ọhun ṣi wa ninu agbara ẹjẹ to n jade lara rẹ nilẹ ibi tí wọn pa a si niwaju banki naa titi di aarọ ọjọ keji, iyẹn ọjọ Iṣẹgun, Tusidee.

Leave a Reply