Awọn ajinigbe bẹ alaga kansu lori, wọn tun ya fidio ẹ

Faith Adebọla

Toro-toro lejo n rin, iwa ọdaju awọn afurasi ọdaran ti wọn n ṣọṣẹ loriṣiiriṣii lagbegbe ilẹ Ibo tun legba kan si i lopin ọsẹ to lọ yii, pẹlu bawọn ajinigbe kan ṣe ji alakooso ijọba ibilẹ Ideato, nipinlẹ Imo, Ọgbẹni Chris Ohizu, ti wọn si gba miliọnu mẹfa Naira owo itusilẹ lọwọ awọn mọlẹbi ẹ. Ṣugbọn kaka ki wọn tu ọkunrin naa silẹ gẹgẹ bii adehun, fọran fidio kan ni wọn fi ṣọwọ sawọn eeyan rẹ, nibi ti wọn ti ṣafihan bi wọn ṣe bẹ alaga kansu naa lori feu, ti wọn si n rẹrin-in, ti wọn n ṣajọyọ lori ẹ bii ẹni pe ẹran ọdun ni wọn pa.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejilelogun, oṣu Kin-in-ni yii, lawọn afurasi naa huwa laabi ọhun, owurọ ọjọ naa ni wọn gba miliọnu mẹfa Naira, nibi ti wọn juwe pe kawọn mọlẹbi oloogbe yii lọọ gbe owo naa si, ti wọn si ṣeleri pe laipẹ sasiko naa lawọn yoo tu ẹni ti wọn mu londe sakata wọn silẹ, iyẹn tawọn ba ti ka owo naa to pe perepere.

Amọ lẹyin wakati diẹ, iyẹn ni bii ọwọ irọlẹ ni fidio kan bẹrẹ si i ja ranyin lori ẹrọ ayelujara, gbogbo awọn ti wọn n wo fidio naa ni wọn n kawọ mọri fun iwa ọdaju tawọn apaayan naa hu ninu rẹ. Wọn da alaga kansu naa dọbalẹ lẹyin ti wọn ti ṣafihan oju rẹ lati fihan pe oun gan-an lẹni naa, wọn ti bọ ẹwu ọrun ẹ, ṣokoto nikan lo ku si i nidii, bẹẹ lọkunrin naa n bẹ wọn tẹkun-tomije pe ki wọn ṣaanu oun, ṣugbọn ẹyin eti wọn ni gbogbo ẹbẹ naa bọ si, wọn da a dọbalẹ, wọn si fi ada ge e lori feu, bẹẹ lẹjẹ eeyan bẹrẹ si i ṣan bii omi, ariwo tawọn apaayan naa si n pa ni pe awọn o ni i gba ki eto idibo kankan waye ni Naijiria, wọn ni gbogbo ọna lawọn maa fi bẹgi dina ipinnu ijọba lati ṣeto idibo lọdun 2023, bẹẹ ko ju oṣu kan lọ mọ sasiko yii ti eto idibo gbogbogboo ọhun maa bẹrẹ.

Ọkan ninu awọn oṣiṣẹ kansu Ideato ti ko fẹẹ darukọ ara ẹ sọ pe aaye ibi ti wọn maa n gbe fidio si lori ikanni wasaapu, eyi ti wọn n pe ni status, ni ọkan ninu awọn ti wọn ṣeku pa ọkunrin naa gbe fidio ọhun si, tawọn eeyan si n pin in kiri.

“Wọn ti pa ọga wa o, a ri fidio bi wọn ṣe pa a lọjọ Sannde. Awọn to pa a gbe e sori ikanni wasaapu wọn, eyi lo jẹ kawọn eeyan tete mọ pe wọn ti pa a ati bi wọn ṣe e pa a nipa oro.

“Fidio naa ko dun-un-wo, o ba ni loju jẹ gidi, irankiran gbaa ni. Ki wọn fokun deeyan lọwọ lẹsẹ, ki wọn kọkọ pa a de idaji, lẹyin naa ni wọn ṣẹṣẹ fada ge ori ẹ jabọ. Iku oro wo lo tun buru to bẹẹ. Wọn dumbu ẹni ẹlẹni bii ẹran ewurẹ, lẹyin ti wọn ti gba miliọnu mẹfa Naira tan,” bẹẹ loṣiṣẹ naa sọ.

Alukoro ileeṣe ọlọpaa ipinlẹ Imo, Ọgbẹni Henry Okoye, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O lawọn ti ṣepade lori ẹ, iwadii to lọọrin si ti n lọ labẹnu. O lawọn maa ri awọn amookunṣika naa mu nibikibi yoowu ti wọn ba sa pamọ si.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Ẹti, Furaidee, ogunjọ, oṣu yii lawọn afurasi agbebọn ti wọn n pe ara wọn ni ‘unknown gunmen’, iyẹn aọn agbebọn ti ẹnikẹni ko mọ, ji alaga ijọba ibilẹ naa gbe, oun atawọn meji mi-in, lẹyin ti wọn ti dana sun ile rẹ to kọ siluu abinibi ẹ, eyi to wa ni Imoko, lagbegbe Arondizuogu, nijọba ibilẹ Ideato, nipinlẹ ọhun.

Latigba naa si lawọn mọlẹbi rẹ ti n ṣaapọn lati tu owo itusilẹ jọ ki wọn le gba ẹni wọn pada laaye, laimọ pe wọn maa pa a lẹyin ti wọn gbowo tan.

Leave a Reply