Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta
DPO teṣan Ọbantoko, ẹkùn Adatan, l’Abẹokuta, SP Alimeke Ignatius, ṣi n gbe apa kiri ori rẹ bayii ni. Eyi ko ṣẹyin bawọn ọmọleewe girama ‘Egba Comprehensive High School’, ati ‘Asérò High School’, l’Abẹokuta, ṣe kọju ija sira wọn lọjọ Wẹsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kọkanla yii, ti wọn si foko fọ DPO yii lori nigba toun atawọn ọmọọṣẹ rẹ lọọ pẹtu saawọ naa.
ALAROYE gbọ pe ija buruku kan lo bẹ sílẹ̀ laarin awọn akẹkọọ naa, ni wọn ba fẹẹ fajulọ han ara wọn. Ija naa kọja agbara awọn tiṣa, nítorí niṣe lawọn akẹkọọ ya bo oju titi, wọn patẹ ija gidi, wọn si tun gbegi dina pẹlu, bẹẹ ni wọn n sọko lu ara wọn.
Eyi lo mu awọn alaṣẹ ileewe pe ọlọpaa, ti DPO atawọn ikọ rẹ fi sare lọ sibẹ lati pana ija, afi bawọn akẹkọọ ṣe foko fọ DPO lori, ti wọn tun ṣe awọn ọmọọṣẹ rẹ leṣe.
Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa Ogun, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O lawọn ko le fọwọ ofin mu awọn akẹkọọ to ṣẹ yii nitori ọmọde ṣi ni wọn labẹ ofin.
O sọ pe awọn kan le fi wọn sibi tawọn yoo ti da wọn lẹkọọ pe ohun ti wọn rawọ le ko dáa ni.