Ọlawale Ajao, Ibadan
Awọn ajinigbe tun pitu ọwọ wọn n’Ibadan lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, pẹlu bi wọn ṣe ya wọ aarin awọn to n wa kusa lọwọ nigboro ilu naa, ti wọn si ji oṣiṣẹ ileefowopamọ kan ati ọkan ninu awọn to n ṣiṣẹ lọwọ nibẹ gbe.
Oṣiṣẹ ileefowopamọ ọhun, Ọgbẹni Ismail Adeoye, ati Ọgbẹni Pópóọlá Isaac to jẹ ọkan ni ninu awọn oṣiṣẹ naa ni wọn ji gbe.
Ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ Aje, Mọnde, niṣẹlẹ ọhun waye nibudo iwakusa to wa labule Dalli, lọna Ibadan si Ijẹbu-Ode.
Agbẹnusọ fún ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CSP Olugbenga Fadeyi, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Awọn afurasi ọdaran kan ti wọn dihamọra pẹlu ibọn lọọ ji awọn eeyan gbe nibi ti wọn ti n ṣiṣẹ lọwọ ni kuari.
Ni nnkan bíi asiko diẹ lẹyin naa ni wọn fi iṣẹlẹ yẹn to awọn ọlọpaa leti ni teṣan wa to wa ni Idi-Ayunrẹ, n’Ibadan.
“Awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ lati gba awọn ti wọn ji gbe silẹ ati lati ri awọn ajinigbe yẹn mu laipẹ jọjọ.”