Faith Adebọla, Eko
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti foju awọn afurasi ọdaran meji kan, Kẹhinde Aroyi, ẹni ọdun mejidinlogun pere, ati Jamiu Shittabay bale-ẹjọ Majisreeti to wa lagbegbe Tinubu, l’Erekuṣu Eko, lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, lori ẹsun pe ọmọọdọ naa lẹdi apo pọ pẹlu awọn meji mi-in lati ṣeku pa ọga rẹ, Abilekọ Abiọla Oluwatosin, majele ni wọn po mọ ounjẹ fun un.
Gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe ṣalaye ni kootu, wọn ni ọmọọdọ ni Kẹhinde atawọn ẹlẹgbẹ rẹ yii n ṣe lọdọ Abiọla to jẹ oniṣowo pataki, owo ilẹ okeere si maa n wa lọwọ rẹ. Owo to wa lọwọ rẹ lasiko iṣẹlẹ naa jẹ ojilerugba din meje owo dọla (233 dollars), ẹgbẹrun marun, ọgọrun-un meje aabọ owo Rupia ti ilẹ Indonesia (546,393 Rupia) ati ẹgbẹrun kan o din mejilelogun owo RMB ti ilẹ China (978 RMB), aropọ gbogbo owo naa si jẹ ẹgbẹrun lọna ojilelẹẹẹdẹgbẹta ati mẹfa, irinwo din meje ti wọn ba ṣẹ ẹ si owo Naira wa (N546,393).
Owo yii ni wọn lafurasi ọdaran yii ri ninu baagi ọga rẹ to fi gbero lati pa a, o sọ fun meji lara awọn ti wọn jọ n ṣe ọmọọdọ, ọkan ninu wọn si juwe ile babalawo kan to wa ninu ọja gorodoomu, lagbegbe Idumọta, lati ba wọn ṣe majele to daju. Jamiu Shittabay lorukọ babalawo naa, o si ṣe majele ọhun fun wọn, o ni ki wọn gbọn lẹbulẹbu naa sinu ounjẹ ọga wọn.
Ọpẹlọpẹ ọkan lara awọn ọmọọdọ naa to fura si wọn, oun lo lọọ ta ọga rẹ lolobo, lọga naa ba wa wọn dẹ, o si ka majele naa mọ Kẹhinde lọwọ nibi to ti n bu u sori ounjẹ to fẹẹ gbe fun un ninu ṣọọbu rẹ to wa ni ṣọọbu kẹtadinlọgọrun, Abibatu Mọgaji Shopping Plaza, to wa n’Idumọta, o gba a lọwọ wọn gẹgẹ bii ẹri, lo ba kọri si tọlọpaa lati lọọ fẹjọ sun, eyi lo mu ki DPO teṣan Ebute Ero, CSP Ademọla Amodu, atawọn ọmọọṣe rẹ lọọ fi pampẹ ofin gbe Kẹhinde ati babalawo rẹ, awọn ọmọọdọ meji yooku ti fẹsẹ fẹ ẹ.
Lasiko iwadii, babalawo naa jẹwọ pe loootọ loun ṣe oogun abẹnugọngọ fun Kẹhinde atawọn ọrẹ rẹ, ṣugbọn oogun to maa mu ki ọga wọn tubọ fẹran wọn denu loun ṣe, ki i ṣe majele rara.
Agbefọba, Inpẹkitọ Koti Aondohemba, ṣalaye nile-ẹjọ pe ẹsun mẹta ti wọn fi kan awọn afurasi ọdaran naa ni igbimọ-pọ lati huwa ibi, ole jija ati igbidanwo lati paayan. Awọn ẹsun yii ni ijiya to gbopọn labẹ isọri ikọkandinlogoje (97), ọrinlerugba ati meje (287), ati isọri irinwo le mọkanla (411), iwe ofin iwa ọdaran tipinlẹ Eko. Wọn lawọn ọtẹlẹmuyẹ ṣi n wa awọn ọmọọdọ to sa lọ.
Ṣa, awọn afurasi naa lawọn o jẹbi. Adajọ ti paṣẹ pe ki wọn gba beeli ọkọọkan wọn pẹlu ẹgbẹrun lọna igba Naira (N200,000) ati ẹlẹrii meji-meji ni iye owo kan naa, tabi ki wọn rọ wọn da sọgba ẹwọn Kirikiri, o si sun igbẹjọ siwaju.