Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Nitori foonu lasan, awọn janduuku kan ti lu akẹkọọ onipele to pari (Final year) ni Fasiti Ifẹ, pa bayii, wọn lo ji foonu ti ki i ṣe tirẹ.
ALAROYE gbọ pe ni ilegbee awọn akẹkọọ, iyẹn Awo Hall, ni wọn ti fẹsun kan akẹkọọ naa pe o ji foonu lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, latibẹ ni wọn si ti bẹrẹ si i lu u lalubami. Bi ilẹ ọjọ Tusidee tun ṣe mọ ni wọn gbe e lọ sibomi-in, nibi ti wọn tun ti n lu u titi di ọsan.
Nigba ti wọn ri i pe ẹmi ti fẹẹ bọ lara rẹ ni wọn sare gbe e lọ sileewosan ẹkọṣẹ iṣegun ti ileewe giga naa, iyẹn Ọbafẹmi Awolowọ Teaching Hospital, Ile-Ife, ṣugbọn ọmọkunrin yii ko ti i gba itọju kankan to fi jade laye.
Nigba to n sọrọ lori igbesẹ naa, Alukoro fasiti ọhun, Abiọdun Ọlarewaju, sọ pe ibanujẹ niṣẹlẹ naa jẹ fun ọga agba ileewe naa, Ọjọgbọn Adebayọ Simeon Bamirẹ.
O ni awọn alaṣẹ ileewe ọhun ti gbe igbimọ kan kalẹ lati wadii iṣẹlẹ ọhun, nitori gbigbimọ-pọ ṣeku pa ẹnikẹni ta ko ofin ileewe naa.
Ọlarewaju sọ siwaju pe awọn ti fi iṣẹlẹ iṣekupani naa to awọn agbofinro leti, wọn si ti bẹrẹ iwadii kiakia. O ni awọn alaṣẹ ba awọn mọlẹbi akẹkọọ naa kẹdun iku ọmọ wọn.
Bakan naa ni aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ Fasiti Ifẹ, Fọlahan Ọlayiwọla, bu ẹnu atẹ lu iwa tawọn janduku naa hu, o ni awọn n duro de esi iwadii awọn ọlọpaa.
Ọlayiwọla fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo awọn ti wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ naa lawọn ọlọpaa gbọdọ fi pampẹ ofin mu, ki wọn si kawọ pọnyin rojọ lori ohun ti wọn ri lọbẹ to mu wọn waro ọwọ.