Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gbogbo awọn eeyan abule kan ti wọn n pe ni Ipoba-Ọjọmu, nijọba ibilẹ Idanre, ni wọn ti sa kuro nile wọn latari iku ọmọkunrin ẹni ọdun mejilelogun kan, Joseph Linus, ẹni ti wọn lu pa lasiko ija igboro to waye labule ọhun lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ nipa iṣẹlẹ ọhun pe ibẹrẹ ọdun ta a wa yii ni ẹni kan ninu awọn eeyan abule naa mu Linus wa gẹgẹ bii onisẹ ọdun.
Ariyanjiyan kan ni wọn lo bẹ silẹ laarin oloogbe ọhun ati ọkunrin kan ti wọn pe inagijẹ rẹ ni Kokoro lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja.
Awọn to wa nibi iṣẹlẹ naa sọ fun wa pe Linus lo kọkọ gba ọkunrin to n ṣiṣẹ age igi gẹdu ọhun leti, eyi to pada yọri si ija laarin awọn alatilẹyin Kokoro ati Linus.
Inu rogbodiyan ta a n wi yii ni wọn lọkunrin lebira ọhun ku si, tawọn eeyan si fẹsun kan Kokoro pe oun lo lu u pa.
Ni kete ti iṣẹlẹ ọhun waye ni Kokoro ti sa lọ, ti ko si sẹni to le sọ ni pato ibi to wọlẹ si ni gbogbo asiko ta a fi n ko iroyin yii jọ lọwọ.
Loootọ lawọn ọlọpaa ti fi pampẹ ofin gbe ẹnikan ti wọn porukọ rẹ ni Temidayọ Ikumọniwọn, ẹni ti wọn lo bẹ Kokoro niṣẹ lati waa maa ba a ge igi, sibẹ gbogbo awọn olugbe abule la gbọ pe wọn ti sa kuro nile wọn, ti olukuluku si ti ba ẹsẹ rẹ sọrọ nitori ibẹru awọn ọlọpaa.
Nigba to n fi idi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmi Ọdunlami, ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori rẹ, ati pe laipẹ laijinna lawọn yoo ri afurasi apaayan to sa lọ mu.
. Abilekọ Ọdunlami ni ohun ti ko tọ, to si lodi sofin ni kawọn eeyan maa ṣe idajọ iwa ọdaran lọwọ ara wọn.
Oku Linus ni wọn lo ṣi wa ni mọṣuari ileewosan ijọba to wa ni Idanre lọwọlọwọ.