Wọn mu Lekan pẹlu ọkọ to ji gbe l’Owode-Ẹgba, lo ba loun ko ti i ji ju mọto mẹta lọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bi awọn mọto mẹta kan yoo ṣe di riri pada ni awọn ọlọpaa Owode-Ẹgba n ṣọna rẹ bayii, wọn si ni awọn yoo ri i dandan pẹlu bọwọ ṣe ti ba ọkunrin kan, Lekan Ogunwọle, to ji wọn lagbala awọn olowo wọn.

Ninu oṣu kẹjọ yii ni awọn ọlọpaa QRS mu Lekan ni ikorita Kọbapẹ, loju ọna Abẹokuta si Ṣagamu. Inu mọto Nissan Sunny ti nọmba ẹ jẹ XA 70 AKM ni wọn ti ri i, oun lo n wa mọto ọhun. Bẹẹ, ẹni to ni mọto naa, Ọladele Oluṣẹgun, ti lọọ fẹjọ sun ni teṣan Owode-Ẹgba pe ibi toun paaki mọto naa si ni wọn ti gbe e lọ lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu keje. Latigba to ti fẹjọ sun yii ni awọn agbofinro ti n wa ọkọ ọhun, ki wọn too ri Lekan ninu ẹ to n wa a kiri lọsẹ to kọja lọhun-un

Awọn ọlọpaa naa da afurasi yii duro, wọn fọrọ wa a lẹnu wo, o si jẹwọ pe oun ji mọto naa nibi ti olowo ẹ gbe e si ni.

Nipa bo ṣe ri kọkọrọ to fi gbe mọto naa kuro nibi to wa, Lekan ṣalaye fun wọn pe oun ni kọkọrọ kan ti wọn n pe ni ‘Master key’ lọwọ, kọkọrọ to le ṣi gbogbo ilẹkun ọkọ naa lo ni oun maa n lo lati fi ṣilẹkun ọkọ ọlọkọ, toun yoo si gbe e lọ. O ni ṣugbọn yatọ si mọto Ọladele yii, mọto mẹta pere naa loun ṣi fi kọkọrọ oun yii ji gbe, ko ti i ju bẹẹ lọ.

Nigba ti wọn beere lọwọ ẹ pe nibo ni kọkọrọ ọhun wa bayii, Lekan ni oun ti sọ ọ nu.

Ohun to wi yii lawọn ọlọpaa naa ṣe leri pe awọn yoo ba a mu nnkan nilẹ, wọn ni o gbọdọ pese kọkọrọ ọhun lọnakọna, bẹẹ lo si gbọdọ mu awọn de ibi ti awọn mọto mẹta to kọkọ ji gbe naa wa.

Ile-ẹjọ ni yoo fi adagba gbogbo ẹ rọ si gẹgẹ bi CP Edward Ajogun ṣe wi, o ni ki wọn ma fi ọrọ Lekan Ogunwọle falẹ, ko tete kawọ pọnyin rojọ ni.

Leave a Reply