*Lo ba loun ko ti i jere kankan nibẹ
Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ko jọ pe mimu ti awọn ọlọpaa mu ọkunrin kan, Moses Nwachukwu, dun un rara. Ohun to han pe o dun un ju ni ti ai ti i ri ere kankan jẹ ninu iṣẹ ayederu oogun pipo to yan laayo, oun naa si fẹnu ara ẹ sọ bẹẹ l’Eleweeran nigba tawọn akọroyin n fọrọ wa a lẹnu wo l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja.
Awọn oogun oyinbo bii ‘Vitamin C, Dizpam ati oogun oniyẹfun lawọn ọlọpaa ba nile Moses to wa l’Ojule kẹẹẹdogun, Opopona Akinbiyi Ojo, l’Ado-Odo, Ọta.
Bakan naa ni wọn tun ba ẹrọ kan ti wọn fi maa n lẹ oogun to ba wa ninu saṣẹẹti pọ, wọn si ba ẹrọ alaagbeletan kan naa nibẹ pẹlu.
Awọn irinṣẹ yii ni wọn ni Nwachukwu fi n po oogun pọ ninu yara rẹ, to si n ta a faye. Ṣugbọn ninu awijare ẹ, ọkunrin Ibo naa sọ pe oun ko tilẹ ti i bẹrẹ si i po oogun pọ, oun ṣẹṣẹ fẹẹ bẹrẹ ni wọn mu oun yii.
Nwachukwu sọ pe nipari oṣu kọkanla, ọdun 2019, loun bẹrẹ si i ba ileeṣẹ apoogun kan ti a ko le fi idi otitọ rẹ mulẹ (Anac Organic lo pe orukọ ileeṣẹ naa), ṣe.
O ni awọn ni wọn n ko oogun wọnyi foun toun si fẹẹ bẹrẹ si i ba wọn ta a. O fi kun un pe boun yoo ṣe maa ba ileeṣẹ naa dowo-pọ daadaa loun n ṣe lọwọ ti Korona fi de, to ba gbogbo nnkan jẹ mọ oun lọwọ, loun ba ko gbogbo irinṣẹ ipoogun naa jọ sibi kan, oun ko mọ bawọn ọlọpaa ṣe gbọ pe oun ni awọn nnkan bẹẹ lọwọ, to fi di pe wọn waa gbe oun nile lori ẹṣun pipo ayederu oogun.
Moses tun sọ pe maṣinni ti wọn fi n lẹ nnkan ti wọn ba nile oun yẹn, ipekere loun fẹẹ maa fi i lẹ papọ ninu lailọọnu rẹ, nitori òwò toun n ronu ẹ lọwọ niyẹn ti wọn fi waa mu oun.
O ni inu oun ko ba dun to ba jẹ oun ti jere nidii oogun pipo naa, ṣugbọn oun ko ti i ri ere kankan jẹ ti wọn fi waa mu oun.
Ọkunrin yii ko ni iwe ẹri apoogun, bẹẹ ni ko kọ iṣẹ naa nibi kankan gẹgẹ bo ṣe wi. O ni iwe mẹwaa loun ka, oun ko lọ si poli tabi fasiti kankan.