Wọn mu ọmọọṣẹ Dapọ Abiọdun to lu awọn oyinbo ni jibiti l’Amẹrika

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Iṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun ti bọ lọwọ ọkan lara awọn oluranlọwọ pataki fun Gomina Dapọ Abiọdun, iyẹn Abidemi Rufai, ẹni ti wọn fẹsun kan pe o lu jibiti ori ẹrọ ayelujara lorilẹ-ede Amẹrika.

Aarọ kutu ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu karun-un yii, ni Gomina Abiọdun paṣẹ pe oun ti da Rufai duro lẹnu iṣẹ naa, yoo ni lati jẹjọ ti wọn fi kan an lorilẹ-ede Amẹrika, ati pe ohun ti wọn sọ pe o ṣe naa ko ni nnkan kan i ṣe pẹlu ijọba oun.

Ọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii, ni wọn mu Abidemi Rufai ni papakọ ofurufu JFK, ni New York, wọn lo ji owo ti iye rẹ jẹ ọọdunrun le aadọta dọla (350,000) lori ayelujara. Washington ni wọn lo ti lu jibiti naa.

A gbọ pe owo naa jẹ ti ẹka to n ri si iṣẹ aabo ilu ‘Employment Security Department’(ESD). Wọn ni wọn ya owo yii sọtọ lati fun awọn eeyan ti ko niṣẹ lọwọ lasiko ti igbele Korona waye ni.

Ṣugbọn Rufai to n pe ara ẹ ni Sandy Tang, fawọn oyinbo, wọ́ owo naa jade lai foju kan awọn to ni in rara. Lọọya agba kan l’Amẹrika, Tessa M. Gorman, lo  fẹsun kan Rufai pe o lo orukọ awọn ẹni ẹlẹni niluu naa, o si fi wọ owo iranwọ jade lakanti ilu.

Wọn ni Abidemi Rufai ko ṣẹṣẹ maa hu iwa jibiti ori ayelujara yii o, wọn lo ti ṣe bẹẹ lawọn ilu bii Hawaii, Wyoming, Massachusetts, New York, Pennsylvania ati Montana, to parọ gba owo iranwọ awọn ẹni ẹlẹni.

Ọmọ Ijẹbu-Ode, nipinlẹ Ogun, ni Abidemi Rufai, o gbiyanju lati lọ sile-igbimọ aṣoju ṣofin ni 2019 gẹgẹ bii oludije. Oṣu kẹjọ, ọdun 2020, ni Gomina Dapọ Abiọdun yan an gẹgẹ bii oluranlọwọ pataki (Senior Special Assistant).

Ṣugbọn bi wọn ṣe mu un fun ẹsun jibiti yii, ijọba Gomina Dapọ Abiọdun sọ ọ di mimọ lati ọfiisi Akọwe iroyin rẹ, Kunle Ṣomọrin, pe awọn ti gba ipo oluranlọwọ pataki naa lọwọ rẹ, ko lọọ jẹjọ ti wọn fi kan an na ki ọrọ ipo rẹ ninu ijọba Ogun too le jẹ sisọ. Wọn ni ọtọ ni Rufai Abidemi, ọtọ nijọba ipinlẹ Ogun.

Ẹni ọdun mejilelogoji ni Abidemi Rufai.

Leave a Reply