Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Bi ki i baa ṣe awọn ọlọpaa ti wọn tete debẹ, diẹ lo ku ki wọn sọko pa ọkunrin kan ti wọn lo gbowo wa sibi ti wọn ti n dibo to feẹ maa fun awọn eeyan ki wọn le dibo fun ẹgbẹ rẹ niluu Ọwọ lasiko ti eto idibo n lọ lọwọ ni Wọọdu kẹrin, ile idibo kẹẹẹdogun, egbe Ọja Shagari, loju ọna Ọwọ si Benin
ALAROYE gbọ pe niṣe ni ọkunrin naa n lọọ ba awọn eeyan naa to si n sọ pe ki wọn ta ibo wọn foun, oun yoo fun wọn lowo.
Bi awọn oludibo to wa nitosi ti kofiri re ni wọn ti ya bo o. Oju ẹsẹ ni wọn ya aṣọ mọ ọn lara. Ohun to sọ fun wọn ni pe oun wa ninu awọn to n mojuto bi eto idibo naa ṣe n lọ si ni. Ṣugbọn nigba ti wọn bẹrẹ si i lu u lo jẹwọ, oju ẹsẹ ni awọn to tẹle e ti kan lugbo.
Ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa to wa nitosi ti wọn gba ọkunrin naa silẹ, awọn oludibo to wa nibẹ fẹẹ sọko pa a ni. Awọn ọlọpaa lo gbe e sinu ọkọ wọn, ti wọn si gbe e lọ si teṣan niluu naa.