Wọn ni DPO yinbọn pa Felix l’Atan-Ọta, ni wọn ba lu oun naa pa

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Ọna mi-in ni wahala to gbode kan nitori ọrọ SARS gba ni teṣan ọlọpaa Atan-Ọta, nipinlẹ Ogun. Idi ni pe wọn ni DPO ibẹ, Salau Abiọdun, ti dagbere faye bayii, nitori ọmọkunrin kan, Felix, ti wọn lo yinbọn lu laaarọ  Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹwaa, lasiko ti awọn eeyan n fẹhonu han laduugbo kan ti ko jinna si teṣan naa.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ki i ṣe DPO nikan lọwọ ba, wọn ni wọn ti dana sun teṣan ọhun, bẹẹ ni nnkan ko ti i fara rọ nibẹ rara.

Ẹnikan to mọ nipa iṣẹlẹ yii ṣalaye pe awọn to n fẹhonu han lori bi ilu ko ṣe fara rọ ni wọn kora wọn jọ l’Atan-Ọta, o ni wọn ko de teṣan ọlọpaa yii, ṣugbọn awọn agbofinro lati teṣan naa ko fẹ ki ikorajọpọ kankan tun waye mọ gẹgẹ bi ijọba ṣe paṣẹ, iyẹn lo jẹ ki wọn mura lati ṣi awọn eeyan naa lọwọ.

Ṣugbọn niṣe ni wahala ṣẹlẹ, to di pe gbogbo ẹ daru, ti wọn si ni DPO yinbọn lu eeyan meji, ti ọmọkunrin kan to n jẹ Felix ninu awọn meji naa si ku lẹsẹkẹsẹ.

Iku Felix lo bi awọn to n wọde naa ninu, ni wọn ba gbinaya, wọn kọju ija si DPO, wọn si fi lilu ṣe e leṣe debii pe iku ni kinni naa ja si ba a ṣe gbọ.

Bo tilẹ jẹ pe awọn kan n sọ pe DPO naa ko ti i ku, ti wọn ni ‘koma’ (ko laju bẹẹ, ni ko mọ ibi to wa) lo wa bayii. Sugbọn iroyin to gbilẹ ju ni pe DPO Salau Abiọdun ti ku.

Lati fidi eyi ti i ṣe ododo mulẹ lori iṣẹlẹ yii, akọroyin wa pe Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ọkunrin naa ko gbe ipe. A tun fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si i, ko fesi titi ta a fi pari iroyin yii.

Leave a Reply