Wọn ni ina ẹlẹntiriiki to ṣẹju ati jẹnẹretọ lo fa ijamba ina to ṣọṣẹ ni Gbagada

Faith Adebọla, Eko

Bo tilẹ jẹ pe inu ibanujẹ nla lọpọ awọn to padanu dukia wọn ninu ijamba ina kan to ṣẹlẹ lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, l’Opopona Ọkẹowo Ṣomọrin, lagbegbe Gbagada, ṣi wa, ajọ to n ri si ọrọ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA, ti fidi ẹ mulẹ pe ina mọnamọna to ṣẹju ki ina naa too bẹrẹ lo ṣokunfa ijamba naa.

Ọga agba ajọ LASEMA, Dokita Olufẹmi Oke-Ọsanyintolu, lo sọrọ naa nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni abajade iwadii tawọn ṣe lẹyin ti wọn pa ina naa tan fihan pe ijamba yii ko ṣẹyin ọkan lara ohun eelo abanaṣiṣẹ to gbana lojiji nigba ti wọn da ina ẹlẹntiriiki pada sagbegbe naa ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ ọjọ naa.

O ni boya ina naa iba ma le to bẹẹ bi ko ba si ti awọn ẹrọ jẹnẹratọ to n ṣiṣẹ lọwọ atawọn ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn paaki papọ nigba ti ijamba naa ṣẹlẹ, tori niṣe lawọn nnkan to n lo epo bẹntiroolu wọnyi n bu gbamu nigba ti ina mu wọn, ti wọn si n fọn ina naa kaakiri.

Olufẹmi ni ọpẹ ni fun Ọlọrun pe ko ṣeni to ku ninu iṣẹlẹ naa, bo tilẹ jẹ pe obitibiti owo ati dukia lo ṣegbe. Ile mẹrin, ati ọpọ dukia ninu eyi ti awọn ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn paaki, ẹrọ jẹnẹretọ, tẹlifiṣan, aṣọ atawọn dukia inu ile lo ṣegbe, ina jẹ wọn run.

O ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ Ọjọruu ni ipe pajawiri wọle sori aago ajọ LASEMA lati fi iṣẹlẹ naa to awọn leti, ẹsẹkeṣẹ si lawọn oṣiṣẹ ajọ naa ti debẹ lati pana naa pẹlu isapa awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana.

Oke-Ọṣanyintolu kẹdun pẹlu awọn ti ijamba naa kan, o si parọwa pe kawọn eeyan tubọ kiyesara lori iṣẹlẹ ina atawọn ohun eelo abanaṣiṣẹ lati dẹkun irufẹ iṣẹlẹ buruku yii.

Leave a Reply