Wọn ni lasiko ti Saraki n ṣe gomina lo fi dukia ijọba yawo fun ileeṣẹ aladaani rẹ ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Oku ti Senetọ Bukọla Saraki, adari ile aṣofin agba tẹlẹ nilẹ yii sin nipinlẹ Kwara ni ẹsẹ rẹ ti yọ sita bayii gẹgẹ bi ajọ to n ri si dukia lorile-ede yii, AMCON, ṣe gbẹsẹ le dukia kan ti Saraki fi duro yawo, iyẹn ileeṣẹ aladaani kan, Shonga Farms Holdings Nigeria limited.

Ọjọru, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni ileeṣẹ to maa n ba ijọba gba gbese ti wọn ba jẹ ẹ, Asset Management Corporation of Nigeria (AMCON), gbẹsẹle dukia kan, iyẹn ileeṣẹ agbẹ Shonga, eyi ti wọn ni Saraki fi yawo lasiko to wa lori aleefa gẹgẹ bii gomina nipinlẹ naa.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, nijọba Kwara sọrọ lori dukia ti wọn gbẹsẹ-le ọhun, wọn ni ṣe ni awọn ijọba to kogba sile sọ ara wọn di akotileta, ti wọn ta oko Shonga naa fun aladaani, ti wọn o si ri oju ipa bi wọn ṣe ta a, ti wọn si n fi Shonga ọhun ṣe boju-boju fun awọn eeyan ipinlẹ Kwara, pe ijọba lo ni i, bẹẹ ko ṣe anfaani kankan fun awọn olugbe ipinlẹ naa.

Ijọba ti bẹrẹ si i dunaa-dura pẹlu ajọ AMCON lori bi dukia ọhun yoo ṣe di ti ijọba ipinlẹ naa pada.

Leave a Reply