Wọn ri foonu olukọ Fasiti Ilọrin to dawati ni Lafiagi 

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ọjọ Ẹti, Furaidee yii, ni wọn ri ẹrọ ibanisọrọ Ọjọgbọn Raphael Babatunde Adeniyi, olukọ ile ẹkọ giga Fasiti Ilọrin to dawati. Ọwọ ọmọ kekere kan niluu Lafiagi, nijọba ibilẹ Edu, nipinlẹ Kwara, ni wọn ti ri i.

Ọjọgbọn Adeniyi to jẹ olukọ ni ẹka eto isiro ni ile ẹkọ giga Fasiti Ilọrin, ni awọn mọlẹbi ati awọn alasẹ ileewe naa kede ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, pe o dawati, lẹyin to dagbere nile pe oun fẹẹ lọọ gba owo ni Banki GT kan n’Ilọrin.

Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ileesẹ ọlọpaa, Ọkasanmi Ajayi, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti sọ pe awọn ti ri foonu Ọjọgbọn naa, lọwọ ọmọ kekere kan ni ilu Lafiagi, nijọba ibilẹ Edu, nipinlẹ Kwara, sugbọn awọn o ti ri Ọjọgbọn Adeniyi titi di akoko yii.

 

Leave a Reply