Wọn ti dajọ iku fun Ibrahim to ge ori ọmọ ọdun meji l’Owode-Ẹgba

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 

Ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ogun ti dajọ iku fun Ibrahim Muhammed, ẹni ọdun mọkandinlogoji, ti wọn fẹsun kan pe o ge ori ọmọ ọdun meji kan lagbegbe Ọfada, Owode-Ẹgba, lọjọ kejila, oṣu kẹrin, ọdun 2014.

Yatọ si ẹsun ipaniyan yii, wọn tun fi ẹsun igbiyanju lati paayan kan Ibrahim. Agbẹnusọ ijọba, Oluwabunmi Akinọla, ṣalaye idi to fi ri bẹẹ. Lọjọ Iṣẹgun to kọja yii lo ṣalaye ni kootu giga to n jokoo l’Abẹokuta pe obinrin kan, Rabi Yakubu, fẹẹ ṣe igbọnsẹ ninu igbo lọjọ naa ni, o si pọn ọmọ rẹ ọkunrin ti ko ju ọmọ ọdun meji lọ sẹyin.

Agbefọba sọ pe nigba ti Rabi ri ibi to ti le ṣegbọnsẹ naa, o sọ ọmọ ẹyin rẹ kalẹ ko le raaye tura daadaa. Nibi to ti n dawọ tẹlẹ ni Ibrahim to ti n tẹle e bọ lai jẹ pe obinrin naa mọ ti yọ si i lojiji pẹlu ọbẹ lọwọ. Niṣe lo si yọ ọbẹ naa si i to fẹẹ fi ge obinrin naa lọrun.

O ni Rabi ja raburabu, ko jẹ ki Ibrahim ge oun lọrun, nibi to si ti n wa ọna lati gba ara ẹ silẹ lo ti bọ sita ninu igbo naa lai le gbe ọmọ rẹ to sọkalẹ mọ, n lo ba kuku kegbajare lọ saarin aba naa pe kawọn eeyan gba oun.

Ko too de pada, Ibrahim ti ge ori ọmọ ti obinrin naa gbe kalẹ, o si sa lọ lẹyin to ṣiṣẹ ibi naa tan. Iya ọmọ fẹjọ sun ni teṣan, wọn si bẹrẹ si i wa Ibrahim.

Nigba tọwọ ba a, Agbefọba sọ pe o jẹwọ pe obinrin kan lo ni koun ba oun wa ori eeyan wa n’Ibadan lati fi ṣetutu ọrọ, ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira(120,000) lo ni obinrin naa loun yoo foun gẹgẹ bii adehun.

Ṣugbọn nigba ti ko ri ori iya ge, to si ti ge ti ọmọ, o gbe e lọ fun onibaara rẹ naa, afi bo ṣe gbe e debẹ tiyẹn ni oun ko fẹ ori ọmọde, ori agbalagba ni adehun awọn.

Eyi lo mu Ibrahim gbe ori naa pada lati lọọ sin in gẹgẹ bi agbẹnuṣọ ṣe wi. Ṣugbọn o pada bọ sọwọ ọlọpaa ni.

Adajọ Ayọkunle Rotimi-Balogun to gbọ ẹjọ naa sọ pe Agbefọba fidi ootọ mulẹ ninu iṣẹlẹ yii kọja ohun teeyan tun le maa ṣiyemeji si, nitori naa lo ṣe paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun Ibrahim Muhammed titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ.

Fun ti Rabi to gbiyanju lati pa, ẹwọn gbere lo ni ki wọn kọ silẹ fun olujẹjọ yii, nitori ẹṣẹ mejeeji ni ijiya ọtọọtọ wa fun labẹ ofin.

Leave a Reply