Wọn ti fole ṣe Taiwo yii o, ko pẹ to pari ẹwọn ọdun marun-un lo tun lọọ jale n’Ijanikin

Faith Adebọla, Eko

Taiwo Sunmọnu lorukọ ọkunrin yii, aipẹ yii ni wọn lo pari ẹwọn ọdun marun-un ti wọn da fun un, ṣugbọn boya ẹwọn ti wọn da fun un tẹlẹ yii ko tẹ ẹ lọrun ni o,  ọkunrin naa tun ti roko ẹwọn mi-in silẹ bayii, afaimọ ni ko ni i pada si ibi to ti n bọ latari bọwọ tun ṣe tẹ ẹ lopin ọsẹ yii lori ẹsun ole jija.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Olumuyiwa Adejọbi to sọrọ nipa iṣẹlẹ yii f’ALAROYE ni ọjọ Abamẹta, Satide yii, lawọn agbofinro tun mu Taiwo, ni nnkan bii aago mọkanla aabọ alẹ, o lawọn ọlọpaa ẹka Ijanikin ni wọn fi pampẹ ofin gbe e.

Bi Adejọbi ṣe wi, awọn araalu kan lo tẹ teṣan ọlọpaa ọhun laago idagiri pe awọn adigunjale kan ti ya bo agbegbe Ọtọ Awori, wọn si n kole lọwọ ni Opopona Ajayi loru ọjọ naa, lawọn ọlọpaa fi gbera lọọ koju wọn nibẹ.

Wọn lawọn adigunjale naa kọkọ fẹẹ ko awọn ọlọpaa loju, wọn bẹrẹ si i yinbọn, lawọn ọlọpaa naa ba fibọn fesi, igba ti eruku ibọn yinyin naa yoo fi rọlẹ, Taiwo Sunmọnu lọwọ ba, awọn yooku sa lọ.

Teṣan ọlọpaa lafurasi naa ti jẹwọ pe oun ṣẹṣẹ tẹwọn de ni, o ni ipari oṣu kọkanla, ọdun to kọja yii, ni wọn da oun silẹ nigba ti ọdun marun-un tile-ẹjọ wọn fun oun pe, o ni oko ole loun lọ nigba naa tọwọ fi ba oun, toun fi dero ẹwọn.

Wọn lo tun jẹwọ pe oun ni awọn ikọ tawọn jọ n jale, o si ti n ran awọn agbofinro lọwọ ki wọn le ri awọn to sa lọ atawọn yooku ninu ikọ rẹ mu.

Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, ti fa iwadii lori iṣẹlẹ yii le awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Panti, ni Yaba, lọwọ, ki wọn le tuṣu desalẹ ikoko lori ẹ.

Bi iwadii ba ti pari, wọn ni Taiwo atawọn tọwọ ba tun tẹ maa kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ, ki wọn le fimu kata ofin.

Leave a Reply