Faith Adebọla
Ifa ajafẹtọ-ọmọniyan nni, Ọmọyele Ṣoworẹ, ti fọ’re bayii, ileejọ ti fun un ni beeli to beere fun, miliọnu lọna ogun naira lo maa fi duro lati le maa tile waa jẹjọ.
Owurọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Abuja fọwọ si ẹbẹ oludasilẹ ati alakooso ileeṣẹ iroyin ori atẹ ayelujara, Sahara Reporters, to ti kọkọ wa lahaamọ awọn agbofinro, kile-ejọ too fi i ṣọwọ sẹwọn lọsẹ to kọja.
Yatọ si miliọnu ogun naira beeli ti wọn bu fun un yii, o tun gbọdọ wa oniduuro meji ni iye owo kan naa, ti wọn si ni dukia to jọju bii ile tabi ilẹ l’Abuja, bẹẹ ni ko gbọdọ ṣere kọja origun mẹrin ilu Abuja, titi ti ẹjọ to n jẹ lọwọ yoo fi pari, aijẹ bẹẹ, awọn agbofinro yoo tun un gbe.
Bakan naa ni wọn fun awọn ẹlẹgbẹ ẹ mẹrin, Juwọn Sanyaolu, Damilare Adenọla, Peter Williams ati Emmanuel Bulus ni beeli, miliọnu kan naira niye owo ti ọkọọkan wọn maa fi duro, wọn si gbọdọ wa oniduuro kọọkan ni iye owo kan naa.
Tẹ o ba gbagbe, alẹ aisun ọdun tuntun, lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2020 to kọja yii, lawọn agbofinro mu Ṣoworẹ atawọn ẹgbẹ ẹ niluu Abuja, nibi ti wọn ti lawọn n ṣe iwọde alaafia kan.
Ẹyin naa ni wọn foju wọn bale-ẹjọ, lara ẹsun tijọba ka si wọn lẹsẹ ni igbimọ-pọ lati dalu ru, apejọ ti ko bofin mu ati riru awọn araalu soke lati dẹyẹ sijọba. Latigba naa nile-ẹjọ ti paṣẹ ki wọn wa lọgba ẹwọn Wuse, l’Abuja.