Wọn ti gbe Sunday Igboho de kootu, awọn ọba Yoruba ni Benin ṣatilẹyin fun un

Jọke Amọri

Ni ba a ṣe n sọrọ yii, ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho ti wa ni ile-ẹjọ kan ti wọn n pe ni Judicial Service Benin, to wa ni Rue 447, Cotonou, Benin 02BP2004 ni orileede Olominira Benin.

Ni nnkan bii aago meji ọsan la gbọ pe wọn tio gbe ajijagbara naa debẹ.

Awọn ọba Yoruba ti wọn wa ni ilẹ Olominira Benin bii mẹtala ati ọpọlọpọ awọn ọmọ Yoruba to n gbe ilu naa la gbọ pe wọn wa nibẹ lati ṣe atilẹyin fun un.

 

Yatọ si Agbẹjọro Yọmi Alliu atawọn mi-in ti wọn jẹ ọmọ Yoruba ti wọn n duro fun Oloye Igboho, wọn ti tun yan ọmọ bibi orileede Benin kan ti a forukọ bo laṣiri, to fi orileede France ṣebugbe lati darapọ mọ awọn ti yoo gba ẹjọ ajijagbara naa ro niwaju adajọ.

Ọmọ bibi ilu Benin ni agbẹjọro yii gẹgẹ bi awọn to mọ bo ṣe n lọ lori ọrọ naa ṣe yọ sọ fun ALAROYE.

Ọkunrin naa jẹ ọkan pataki ninu awọn agbẹjọro to dantọ niluu naa, oun naa si yoo si ṣaaju awọn agbẹjọro ti yoo gbẹjọ rẹ ro niwaju adajọ.

ALAROYE gbọ pe orileede France lo n gbe, to ti n ṣiṣẹ amofin, ṣugbọn o ni ileeṣẹ ofin rẹ ni orileede Benin, bẹẹ lo si jẹ ọmọ Yoruba orileede naa.

 

 

Leave a Reply