Faith Adebọla
Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe wọn ti gbe gbaju-gbaja ajafẹtọọ ọmọniyan to n ja fun iran Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho, lọ si ile-ẹjọ giga kan ni ilu Cotonou, lorileede Benin.
Ile-ẹjọ kan ti wọn n pe ni Judicial Service Benin, to wa ni Rue 447, Cotonou, Benin 02BP2004, ni wọn gbe e lọ.
Ọkan lara ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o fẹẹ fi ayederu iwe irinna Naijiria rin irinajo.
Awọn agbẹjọro ti wọn jẹ ọmọ Naijiria ti wọn wa lawọn ilu bii France, London, Germany ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn ti peju sile-ẹjọ naa.
ALAROYE yoo maa fi bo ba ṣe n lọ to yin leti.