Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lẹyin iku ojiji to pa ọkunrin kan, Kayọde Badru, to ṣẹṣẹ ti Dubai de, ti ina abẹla jo o pa ni ṣọọṣi Sẹle, Imọlẹ Parish, l’Alagbado, Eko, wọn ti ju wolii to wọn lọfinda si i lara satimọlẹ, iyẹn Wolii Felix Alebioṣu.(Ebony).
Yatọ si Wolii Felix, awọn mi-in tiṣẹle naa ṣoju wọn ti wa lahaamọ ọlọpaa ni Panti pẹlu,wọn n ṣalaye ohun ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ aburu naa. Bẹẹ la gbọ pe awọn mi-in ti sa lọ.
Eeyan nla ni Oloogbe Kayọde Badru nipinlẹ Eko ati lorilẹ-ede Dubai, Dubai naa lo ti de si Naijiria laipẹ yii. Awọn ọmọ ijọ Sẹlẹ to ran lọwọ ninu ẹkọ wọn (O ran wọn lọ si Academy For Innovative Art and Technology) (ACIATECH) lo waa ba ṣajọyọ ni Ṣọọṣi Imọle Parish to wa ni Nureni Yusuf, l’Alagbado.
Isin ọpẹ ni wọn lo n ṣe lọjọ naa ti i ṣe ọjọ Mọnde, ọjọ kẹta, oṣu karun-un yii, ninu ṣọọṣi naa. Abẹla meje lo mu dani, bẹẹ lo kunlẹ saarin awọn wolii Sẹlẹ to fẹẹ gbadura fun un.
A gbọ pe Wolii Alebioṣu ti wọn tun n pe ni Ebony, lo wọn lọfinda si i lara. Bi nnkan ṣe yiwọ lojiji niyẹn, ti lọfinda ti wọn da si i lara mu ina abẹla maa jo ju, ina naa si n jo Kayọde, nnkan si ṣe!
Ẹnikan ninu awọn ọmọ ijọ naa to ni iṣẹlẹ yii ṣoju oun ṣalaye pe ina naa ko jo Oloogbe yii pupọ ti wọn fi bomi pa a. O ni ẹsẹkẹsẹ ni wọn si gbe e lọ sileewosan Jẹnẹra to wa ni Gbagada, lẹka ibi ti wọn ti n tọju awọn tina ba jo.
O lo wa nibẹ lọjọ keji, iyatọ diẹ si wa lara ẹ, nitori alaafia ba a. Afi bo ṣe di lọjọ kẹta iṣẹlẹ naa ti ọkunrin olowo Dubai naa jade laye.
Ẹlomi-in to tun sọ sọrọ yii sọ pe iku to pa Kayọde Badru yii lọwọ kan abosi ninu. O ni ṣugbọn oju Oluwa lo to ohun ti eeyan ko ri.
Wọn tilẹ ni Oloogbe naa funra ẹ sọrọ nigba to wa lọsibitu, wọn lo ni ṣe boun yoo ṣe pari aye oun ree, bẹẹ, inu ire lo gbe oun de Naijiria, oun ko mọ pe bi yoo ti ri ree.
Ṣugboọ ohun ti ọpọ eeyan n sọ lori iṣẹlẹ naa ju ni pe ko si ọwọ aye kankan nibẹ, wọn ni lọfinda tawọn Sẹlẹ n lo ni eroja to le mu ki ina gba lojiji ninu. Wọn ni bii igba teeyan n ṣana lẹgbẹẹ bẹntiroolu lawọn lọfinda mi-in ri. Wọn ni lọfinda lo pe ina abẹla mọra, to si tun jẹ pe aṣọ sutana fẹlẹfẹlẹ ni Oloogbe wọ, wọn ni ohun to jẹ ko gbina niyẹn.
Awọn olori ijọ Sẹlẹ paapaa ti fi atẹjade sita lori iṣẹlẹ yii, eyi ti wọn fi sita lọjọ Satide, ọjọ kẹjọ, oṣu karun-un yii. Ohun ti atẹjade naa sọ ni pe kawọn wolii maa fi omi la lọfinda ki wọn too wọn ọn siiyan lara, nitori ina abẹla.
Atẹjade ti AVSE Stephen Adeniyi fọwọ si lorukọ Ẹni-ọwọ Emmanuel Mobiyina Oshoffa, ṣalaye pe lilo lọfinda lai fi omi la a ki i ṣe aṣa Sẹlẹ, Baba Oshoffa to da ijọ naa silẹ ko si kọ ẹnikẹni niru ẹ, wọn ni aṣa ajeji ni.
Wọn ni ẹka Sẹlẹ to ba lodi sofin yii ni yoo da nikan ro ẹjọ ẹ bi wahala ba de, iyẹn eyikeyii ijọ naa tabi pasitọ to ba tun n lo lọfinda lai fi omi lu u lati asiko yii lọ.