Wọn ti mu Jide, ọkan ninu awọn ogbologboo adigunjale to n yọ awọn eeyan Akurẹ lẹnu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọkan ninu awọn ogbologboo adigunjale to n yọ awọn eeyan ilu Akurẹ lẹnu lọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ lọsẹ to kọja yii.

Afurasi ọhun ti wọn porukọ rẹ ni Jide Adewale lọwọ tẹ lẹyin toun atawọn ẹgbẹ rẹ ninu iwa ọdaran tun lọọ ja ileepo nla kan  l’Akurẹ lole owo nla atawọn ẹru mi-in nnkan bii aago mẹfa idaji ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja lọhun-un.

Ni kete ti wọn ti fi iṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa leti ni wọn ti n tọpasẹ awọn oniṣẹẹbi naa ti wọn si n sọ wọn lọwọ lẹsẹ titi tọwọ fi tẹ ọkan ninu wọn.

Lati bii oṣu meji sẹyin lara o ti rọ okun mọ ti ko si tun rọ adiyẹ niluu Akurẹ, akọlu tawọn adigunjale n ṣe sawọn ileepo kan ti ilẹ ba ti n su lọ.

Gbogbo ileepo ti ikọ awọn adigunjale naa n ṣabẹwo si ni wọn ti n ko wọn lẹru pẹlu obitibiti owo, ti wọn si tun n yinbọn pa gbogbo ọlọdẹ ti wọn ba ti laju ri.

Ibẹru akọlu tawọn janduku naa n ṣe lo ṣokunfa bi ẹgbẹ awọn alagbata epo ṣe fohun ṣọkan lati maa ti lẹkun ileepo wọn laago meje alẹ.

 

Leave a Reply