Ijọba fi ofin de ẹgbẹ ẹlẹja ni ipinlẹ Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Gomina Rotimi Akeredolu ti kede fifi ofin de ẹgbẹ awọn to n ta ẹja jake-jado ipinlẹ Ondo lati dena rogbodiyan to fẹẹ bẹ silẹ laarin wọn.

Arakunrin ni oun gbe igbesẹ naa ni idahun si ibeere awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun lasiko ti wọn n fẹhonu han ta ko awọn aṣaaju ẹgbẹ wọn niluu Akurẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ ta a wa ninu rẹ yii.

Ọgọọrọ awọn obinrin ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ ẹlẹja ni wọn kora wọn jọ lọjọ naa lati fẹhonu wọn han lori ọwọ lile ti wọn lawọn asaaju ẹgbẹ fi n mu awọn.

Ọja Ọba eyi ti wọn tun n pe ni Ẹrẹkẹsan ni wọn ti bẹrẹ ifẹhonu han naa, ti wọn si lọọ pari rẹ si ọfiisi gomina to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ.

Ohun tawọn olufẹhonu han yii ṣaa n kọ lorin ni pe kijọba Akeredolu ba awọn fagi le ẹgbẹ ẹlẹja, wọn ni awọn ko fẹ ohun to jọ bẹẹ mọ nitori inira tí awọn aṣaaju ẹgbẹ n mu ba iṣẹ awọn.

Wọn ni ohun to bí awọn ninu ju ni ti abilekọ kan, Dorcas Ajayi, to pade iku ojiji nibi to sapamọ si nitori ẹgbẹrun kan naira pere ti eyi towo rẹ ku to fẹẹ san sínú ẹgbẹ.

Abilekọ Blessing Johnson to gba ẹnu awọn ẹgbẹ rẹ sọrọ ni gbogbo ile-ẹja to wa l’Akurẹ ati agbegbe rẹ lawọn aṣaaju awọn ti fun lofin pe wọn ko gbọdọ tẹja fun oloogbe ọhun nigba to wa laye nitori ẹgbẹrun kan naira owo ẹgbẹ tí ko ti i san tan.

O ni ọkan ninu awọn ile-ẹja naa lo wa lọjọ kan ti awọn ti ẹgbẹ yan gẹgẹ bii agbowo-ipa fi de, bi obinrin naa ṣe rí wọn lo sare sa kuro nibi to duro si, to si lọọ fara pamọ nile alapa kan to wa nitosi.

O ni lẹyin bii isẹju diẹ to fi wá nibẹ to si n reti igba tawọn ọlọpaa ẹgbẹ fẹẹ lọ ni ile ọhun deedee yẹ lojiji, ti ogiri rẹ si wo lu u mọlẹ́ ibi to jokoo si.

Gbogbo eyi lo ni awọn ro papọ tawọn fi pinnu ati waa fohun to n sẹlẹ to gomina leti ko le tete ba awọn wa nnkan ṣe si iwa ọdaju tawọn asaaju awọn n hu.

Oludamọran agba fun gomina lori eto aabo, Alaaji Jimoh Dojumọ, lo gba ẹnu ọga rẹ ba awọn olufẹhonu han naa sọrọ.

Dojumọ fi da awọn olufẹhonu naa loju pe ijọba maa ṣewadii bi ọrọ naa ṣe jẹ.

Lẹyin o rẹyin nijọba ṣẹṣẹ kede fífi ofin de ẹgbẹ ọhun titi ohun titi dọjọ mi-in ọjọ ire.

 

 

Leave a Reply