Ẹwọn n run lori Kelvin yii o, ọmọ ọdun mẹsan-an lo fipa ba lo pọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Boya lọkunrin ẹni ọdun marundinlogoji kan, Kelvin Abugu, ko ni i fẹwọn jura latari ẹsun pe o fi tipatipa ba ọmọ ọdun mẹsan-an pere lo pọ.

Iya ọmọdebinrin ọhun, Abilekọ Agness Emmanuel, lo kọkọ ṣakiyesi ẹjẹ to wa lara awọtẹlẹ ti ọmọ rẹ wọ lọjọ I’Aiku, Sannde, ọsẹ to kọja lọhun-un.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe fun ọmọ ta a forukọ bo laṣiiri ọhun lo ti jẹwọ pe Kelvin to jẹ aladuugbo awọn lo fi ika ro oun nidii ko too tun ki kinni rẹ si i.

Pẹlu ibinu lobinrin naa fi mori le tesan lati lọọ fẹjọ afurasi afipabanilopọ ọhun sun awọn agbofinro.

Nigba ti Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Bọlaji Salami, fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ ni, lati bii ọsẹ meji sẹyin ni afurasi naa ti wa lọdọ awọn, ṣugbọn ti ọrọ iyansẹlodi awọn oṣiṣẹ kootu to n lọ lọwọ ko ti i jẹ kawọn gbe e lọ sile-ẹjọ.

Leave a Reply