Awọn agbebọn kọ lu ọkọ tí wọn fi n ko awọn ọmọọleewe l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ori lo ko awọn akẹkọọ atawọn osiṣẹ ileewe aladaani kan, Chimola Schools, yọ lọwọ awọn agbebọn kan to fẹẹ ji wọn gbe laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ẹnikan to mọ nipa iṣẹlẹ naa pe ni nnkan bii aago meje aarọ, lasiko ti olukọ ọhun ati awakọ bọọsi naa n kaakiri agbegbe ẹsiteeti to wa ni Ọba-Ile, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, lati ko awọn akẹkọọ gẹgẹ bii iṣe wọn laaarọ niṣẹlẹ ọ̀hún waye.
O ni lojiji lawọn agbebọn bii mẹjọ yí ọkọ bọọsi naa ka pẹlu ọkada tí wọn gun, wọn kọkọ fi tipatipa wọ awakọ bọọsi ọhun silẹ ki ọkan ninu awọn ajinigbe ọhun too bọ si aaye rẹ, to si wa ọkọ naa lọ pẹlu pẹlu oṣiṣẹ obinrin kan ti wọn jọ wa ninu ọkọ.
O ni ohun t’Ọlọrun fi ko wọn yọ ni pe awakọ ọhun ko ti i gbe akẹkọọ kankan ki akọlu naa too waye, ọmọ akọkọ lo ṣẹṣẹ fẹẹ lọọ gbe lasiko ti wọn da wọn duro nitori pe o ṣee ṣe ko jẹ nitori ati ji awọn akẹkọọ ileewe ọhun ko gan-an lawọn agbebọn naa fi ṣe akọlu si ọkọ wọn.
Wọn ti fi Ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún to awọn ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo leti bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i sọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ ijinigbe naa lasiko ta a n kọ iroyin yii jọ lọwọ.
Oludasilẹ ileewe ọhun, Abilekọ Bọlatito Akindẹmọwọ, ni ko sẹni ti wọn ji gbe ninu awọn akẹkọọ naa.
O ni oun ti fi iṣẹlẹ ọhun to awọn ẹsọ alaabo leti fun igbesẹ to yẹ.
Bakan naa la tun ri i gbọ pe awọn agbebọn ọhun ti yọnda ọsiṣẹ-binrin ti wọn gbe sal ọ bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i mọ ibi tí ọkọ ti wọn ja gba wọlẹ si.
Oṣiṣẹ ọhun torúkọ rẹ n jẹ Peace la gbọ pe o fẹsẹ ara rẹ rin pada sinu ọgba ileewe naa ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ, ìyẹn lẹyin wakati meji o le diẹ tí wọn ti ji i gbe sa lọ.

Leave a Reply