Aderohunmu Kazeem
Awọn meje kan nile-ẹjọ Majisireeti to wa ni Ebute-Mẹta, l’Ekoo, ti paṣe pe ki wọn lọọ fi wọn pamọ sọgba ẹwọn n’Ikoyi lori ẹsun ifipabanilopọ.
Ọmọ ọdun mọkanla kan, Favour Okechukwu, ni wọn sọ pe awọn eeyan yii fipa ba lo pọ lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ni Nọmba 4, Ọlanrewaju, niluu Ejigbo, l’Ekoo.
Iṣẹ ni iya ọmọ naa ran an ti wọn fi dena de e, ti wọn si wọ ọ lọ si ile akọku kan, nibi ti awọn mejeeje ti fipa ba a lo pọ. A gbọ pe ọmọ naa ku mọ wọn lọwọ nibi ti wọn ti n ba a ṣere buruku yii.
Ọga ọlọpaa to fẹsun ọhun kan wọn, Kehinde Ọlatunde, sọ fun ile-ẹjọ pe awọn eeyan wọnyi lo ṣiṣẹ ibi ọhun; Ajom Tabi, eni ọdun mẹtadinlogoji; Ọmọbọlanle Olowookere, ẹni ọdun mọkanlelogoji; Aliu Bilyamin, ọmọ ọdun mẹrinlelogun; Emmanuel Okon, ẹni ọdun mẹrinlelogun 24; Bọlarinwa Ọlamilekan, ẹni ọdun mẹrinlelogun; Badmus Abdulateef, ẹni ogun ọdun; Azeez Quadri, ọmọ ọdun mejilelogun; ati Sunday Ọdunayọ, ọmọ ọdun mejilelogun.
Ẹsun onikoko mẹta ni wọn ka si wọn lẹsẹ, ifipabanilopọ, ipaniyan ati ṣiṣe ọmọ ti ko ti i mọ ọkunrin baṣubaṣu.
Adajọ Majisireeti naa, O.G. Oghre, kọ lati gba ẹbẹ wọn, bẹẹ lo ti pa awọn ọlọpaa laṣẹ lati da ẹjọ wọn pada si ẹka to n ṣeto idajọ l’Ekoo.
Ọkan ninu awọn afurasi ọhun ti ile-ẹjọ fun ni beeli ni Olowookere, wọn ti ni ko wa oniduuro meji wa pẹlu idaji miliọnu, ẹni kọọkan wọn nigba ti agbẹjọro ẹ, Spurgeon Ataene, sọ fun ile-ẹjọ pe ko mọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ ọhun.
Ọjọ kejidinlogun, oṣu kọkanla yii, ni ẹjọ mi-in yoo tun waye lori ọrọ ọhun.