Wọn ti yọ alaga APC Kwara nipo

Stephen Ajagbe, Ilorin

Wahala to n ṣẹlẹ lẹgbẹ oṣelu to n ṣejọba nipinlẹ Kwara, APC, ti gbọna mi-in yọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, bi igbimọ alaamojuto apapọ ẹgbẹ naa l’Abuja ṣe kede iyọnipo Bashiru Ọmọlaja Bọlarinwa (BOB) to jẹ alaga ẹgbẹ naa ni Kwara, ti wọn si fi Abdullahi Samari rọpo rẹ loju ẹsẹ.

Ọrọ naa ti n fi logbologbo bii ẹpọn agbo lati ibẹrẹ ọsẹ yii, bẹẹ lawọn kan to jẹ alatilẹyin BOB n naka abuku si Gomina Abdulrahman Abdulrazaq, ẹni ti wọn fẹsun kan pe o wa nidii bi ẹgbẹ ṣe yọ alaga naa nipo.

Lara awọn to ti gbe pẹrẹgi ija kana pẹlu gomina ni awọn to duro lẹyin Minisita feto iroyin, Lai Mohammed, ati akẹgbẹ rẹ, Minisita keji feto irinna, Rukayat Gbemiṣọla Saraki.

Adari igun to n ṣatilẹyin fun BOB, iyẹn Akọgun Iyiọla Oyedepo, ti ta ko iyọnipo alaga naa. Wọn ni gbogbo ọna lawọn yoo fi ba gomina fa a ti yoo to ara wọn.

ALAROYE gbọ pe awọn eeyan ọhun ya bo olu ile ẹgbẹ APC l’Abuja lati pe fun yiyi ipinu naa pada, ṣugbọn wọn ko raaye ri alaga apapọ ẹgbẹ naa.

Wọn ni akọwe apapọ ẹgbẹ, Sẹnatọ John Akpanudeodehe, sọ fun wọn pe ẹgbẹ gbe igbesẹ naa lati le tẹ Gomina Abdulrahman Abdulrazaq lọrun nitori pe o ti loun ko le ba BOB ṣiṣẹ papọ.

Oyedepo ni, “Beba lasan ni lẹta iyansipo ti wọn fun Abdullahi Samari, ko wulo fun nnkan kan. Ohun tẹgbẹ ṣe yii ko le fẹsẹ mulẹ ni Kwara laelae. Nigba ta a sọ fun akọwe apapọ ẹgbẹ pe igbesẹ yiyọ BOB nipo yoo ba ẹgbẹ jẹ nipinlẹ Kwara, o ni iyẹn ko kan awọn.”

Ọkan lara awọn to sun mọ Gomina Abdulrahman pẹkipẹki, Kunle Sulaiman, ni ko si ootọ ninu ẹsun ti wọn fi n kan gomina pe o wa nidii yiyọ BOB nipo. O ni ọrọ yoo sọ ara rẹ lasiko tawọn ba pade alaga apapọ ẹgbẹ naa, ibi ipade apapọ ẹgbẹ to maa waye l’Abuja lawọn eeyan yoo ti mọ awọn ojulowo adari ẹgbẹ ni Kwara.

Ṣugbọn awọn alatilẹyin BOB ti leri o, wọn lawọn ti jọ tẹsẹ bọ ṣokoto kan naa pẹlu gomina, awọn yoo ri i pe o fipo naa silẹ. Wọn ni bawọn ṣe fọwọsowọpọ lati le iṣejọba Saraki danu lọdun 2019 lawọn yoo tun gbimọ-pọ lati juwe ọna ile fun un.

Leave a Reply