Wọn tun ji awọn eeyan meji gbe lọjọ ọdun Itunu aawẹ n’Ikaram Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Eeyan meji ni wọn tun ji gbe niluu Ikaram Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ ta a wa yii.

Ọkan ninu awọn ti wọn ji gbe ọhun, ẹni tawọn eeyan mọ si Gbodi, ni wọn kọkọ ji gbe loju ọna marosẹ Oke-Agbe si Ikaram, lasiko to n pada sile lati oko to ti lọọ ṣiṣẹ nigba ti wọn ji ẹni keji gbe nitosi ibi ti wọn ti gbe awọn oyinbo kan lọ ni nnkan bii ọsẹ mẹrin sẹyin.

Ninu alaye ti Akala ti Ikaram, Ọba Andrew Momodu ṣe fun akọroyin ALAROYE nipa ẹnikeji tí wọn ji gbe loju ọna marosẹ Akunnu si Ikaram Akoko.

O ni ọkunrin ọhun ati ẹnikan ni wọn jọ wa lori ọkada lọjọ naa ki wọn too bọ sọwọ awọn ajinigbe ti wọn sina ibọn bo wọn.

Akala ni wọn ji ẹnikan gbe, nigba ti wọn fi ẹnikeji rẹ ti ibọn ba lẹsẹ silẹ ninu agbara ẹ̀jẹ̀ to wa.

Ọkan ninu awọn ti wọn ji gbe naa lo ni awọn to ji i gbe tí kan sawọn ẹbi rẹ, tí wọn si n beere fun miliọnu mẹwaa naira ki wọn too tu u silẹ.

Ọba Momodu rọ ijọba lati tete wa nnkan ṣe sọrọ awọn ajinigbe to n fojoojumọ soro bíi agbọn lagbegbe naa nitori pe ọkan awọn araalu ko fi bẹẹ balẹ mọ latari iṣẹ ibi ti wọn n ṣe.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, ni awọn ẹsọ alaabo ti n lepa awọn oniṣẹẹbi ọhun, ki wọn baa le ri awọn mejeeji tí wọn ji gbe gba pada lọwọ wọn.

Leave a Reply