Ka ma purọ, ojusaaju ati eru pọ ninu ijọba yii – Gomina Bauchi

Faith Adebọla

“Ka ma purọ, ojuṣaaju, aiṣedajọ ododo ati aiṣẹtọ pọ ninu ijọba to wa lode yii, o si fara han. Iwa jibiti ati ajẹbanu pọ, o si ti n mu kawọn araalu gbagbọ pe awọn kan ti wa tijọba n wo bii ẹni tawọn o le fọwọ kan. Awọn kan ti sọ ara wọn di oriṣa akunlẹbọ lorileede yii, ti ko sẹni to le bi wọn leere ohunkohun ti wọn ba ṣe laida.”

Gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed lo ṣiṣọ loju eegun ọrọ yii nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ ni Yidi, lasiko ayẹyẹ ọdun Itunu aawẹ to waye l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, nipinlẹ naa.

Mohammed ni: “Ootọ ọrọ wa ninu ohun tawọn gomina ipinlẹ Guusu orileede wa n sọ, o ti han pe ijọba n gbe aparo kan ga ju ọkan lọ, wọn n fun awọn ẹya kan lafiyesi ju omi-in lọ, wọn si ti mu kawọn kan ri ara wọn bii pe ohunkohun ti wọn ba ṣe, aṣegbe ni. “Ohun ta a mọ lorileede yii ni pe ijọba fẹdira (federal) la wa, ilana ibi ko ju ibi, ẹya kan o ju ekeji lọ lo si yẹ ka maa lo, ki nnkan si wa lọgbọọgba paapaa lori iyansipo awọn lọgaa lọgaa ileeṣẹ ati ẹka ijọba, lati apapọ titi de ibilẹ.

“Nigba tijọba apapọ ko ba pin nnkan bo ṣe yẹ, bawo leeyan ṣe fẹẹ reti kijọba ibilẹ pin in daadaa. Iru awọn nnkan wọnyi lo n mu kawọn eeyan sọ pe awọn fẹẹ ya kuro, awọn o ṣe Naijiria mọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ipa tiru iwa bẹẹ n ni lori awọn eeyan ki i daa. Afi tawọn adari ijọba ba yọ ojusaaju ati eru kuro ninu iyasipo ati iṣẹjọba, ọrọ-aje orileede yii o le sunwọn si i.

Gomina naa tun ṣekilọ pe kawọn eeyan ṣọ ọrọ ti wọn maa maa sọ lasiko yii, ki wọn maa sọ ohun to le mu kara kan awọn araalu tabi to le da ijọgbọn silẹ.

Leave a Reply